Gẹn 4:1-4
Gẹn 4:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
ADAMU si mọ̀ Efa aya rẹ̀; o si loyun, o si bí Kaini, o si wipe, Mo ri ọkunrin kan gbà lọwọ OLUWA. O si bí Abeli arakunrin rẹ̀. Abeli a si ma ṣe oluṣọ-agutan, ṣugbọn Kaini a ma ṣe aroko. O si ṣe, li opin ọjọ́ wọnni ti Kaini mu ọrẹ ninu eso ilẹ fun OLUWA wá. Ati Abeli, on pẹlu mu ninu akọbi ẹran-ọ̀sin ani ninu awọn ti o sanra. OLUWA si fi ojurere wò Abeli ati ọrẹ rẹ̀
Gẹn 4:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó yá, Adamu bá Efa, aya rẹ̀, lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Ó ní, “Pẹlu ìrànlọ́wọ́ OLUWA, mo ní ọmọkunrin kan,” ó sọ ọmọ náà ní Kaini. Lẹ́yìn náà, ó bí ọmọkunrin mìíràn, ó sọ ọ́ ní Abeli. Iṣẹ́ darandaran ni Abeli ń ṣe, Kaini sì jẹ́ àgbẹ̀. Nígbà tí ó yá, Kaini mú ninu èso oko rẹ̀, ó fi rúbọ sí OLUWA. Abeli náà mú àkọ́bí ọ̀kan ninu àwọn aguntan rẹ̀, ó pa á, ó sì fi ibi tí ó lọ́ràá, tí ó dára jùlọ lára rẹ̀ rúbọ sí OLUWA. Inú OLUWA dùn sí Abeli, ó sì gba ẹbọ rẹ̀
Gẹn 4:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Adamu sì bá aya rẹ̀ Efa lòpọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí Kaini. Ó wí pé, “Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ OLúWA ni mo bí ọmọ ọkùnrin.” Lẹ́yìn náà, ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn tí a pè ní Abeli. Abeli jẹ́ darandaran, Kaini sì jẹ́ àgbẹ̀. Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Kaini mú ọrẹ wá fún OLúWA nínú èso ilẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n Abeli mú ẹran tí ó sanra wá fún OLúWA nínú àkọ́bí ẹran ọ̀sìn rẹ̀. OLúWA sì fi ojúrere wo Abeli àti ọrẹ rẹ̀