Gẹn 37:12-23

Gẹn 37:12-23 Bibeli Mimọ (YBCV)

Awọn arakunrin rẹ̀ si lọ lati bọ́ agbo-ẹran baba wọn ni Ṣekemu. Israeli si wi fun Josefu pe, Ni Ṣekemu ki awọn arakunrin rẹ gbé mbọ́ ẹran? wá, emi o si rán ọ si wọn. On si wi fun u pe, Emi niyi. O si wi fun u pe, Mo bẹ̀ ọ, lọ wò alafia awọn arakunrin rẹ, ati alafia awọn agbo-ẹran; ki o si mú ihin pada fun mi wá. Bẹ̃li o si rán a lati afonifoji Hebroni lọ, on si dé Ṣekemu. Ọkunrin kan si ri i, si wò o, o nrìn kakiri ni pápa: ọkunrin na si bi i pe, Kini iwọ nwá? On si wipe, Emi nwá awọn arakunrin mi: mo bẹ̀ ọ, sọ ibi ti nwọn gbé mbọ́ agbo-ẹran wọn fun mi. Ọkunrin na si wipe, Nwọn ti lọ kuro nihin; nitori mo gbọ́, nwọn nwipe, ẹ jẹ ki a lọ si Dotani. Josefu si lepa awọn arakunrin rẹ̀, o si ri wọn ni Dotani. Nigbati nwọn si ri i lokere; ki o tilẹ to sunmọ eti ọdọ wọn, nwọn di rikiṣi si i lati pa a. Nwọn si wi fun ara wọn pe, Wò o, alála nì mbọ̀wá. Nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ki a si wọ́ ọ sọ sinu ọkan ninu ihò wọnyi, awa o si wipe ẹranko buburu li o pa a jẹ: awa o si ma wò bi alá rẹ̀ yio ti ri. Reubeni si gbọ́, o si gbà a li ọwọ́ won; o si wipe, Ẹ máṣe jẹ ki a gbà ẹmi rẹ̀. Reubeni si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe ta ẹ̀jẹ, ṣugbọn ẹ sọ ọ sinu ihò yi ti mbẹ li aginjù, ki ẹ má si fọwọkàn a; nitori ki o ba le gbà a lọwọ wọn lati mú u pada tọ̀ baba rẹ̀ lọ. O si ṣe nigbati Josefu dé ọdọ awọn arakunrin rẹ̀, nwọn bọ́ ẹ̀wu Josefu, ẹ̀wu alarabara aṣọ ti o wà lara rẹ̀

Gẹn 37:12-23 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ kan àwọn arakunrin rẹ̀ ń da agbo aguntan baba wọn lẹ́bàá Ṣekemu, Israẹli bá pe Josẹfu, ó ní, “Ǹjẹ́ Ṣekemu kọ́ ni àwọn arakunrin rẹ da ẹran lọ? Wò ó, wá kí n rán ọ sí wọn.” Josẹfu bá dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Israẹli sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́, lọ bá mi wo alaafia àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ati ti àwọn agbo ẹran wá, kí o sì tètè pada wá jíṣẹ́ fún mi.” Israẹli bá rán an láti àfonífojì Heburoni lọ sí Ṣekemu. Níbi tí ó ti ń rìn kiri ninu pápá ni ọkunrin kan bá rí i, ó bi í pé, “Kí ni ò ń wá?” Josẹfu dáhùn pé, “Àwọn arakunrin mi ni mò ń wá, jọ̀wọ́, ǹjẹ́ o mọ ibi tí wọ́n da agbo ẹran wọn lọ?” Ọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Wọ́n ti kúrò níhìn-ín, mo gbọ́ tí wọn ń bá ara wọn sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ sí Dotani.’ ” Josẹfu bá tún lépa wọn lọ sí Dotani, ó sì bá wọn níbẹ̀. Bí wọ́n ti rí i tí ó yọ lókèèrè, kí ó tilẹ̀ tó súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn, wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọn láti pa á. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wí fún ara wọn pé, “Ẹ wò ó, alálàá ni ó ń bọ̀ yìí! Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa á, kí á wọ́ ọ sinu kòtò kan, kí á sọ pé ẹranko burúkú kan ni ó pa á jẹ, kí á wá wò ó bí àlá rẹ̀ yóo ṣe ṣẹ.” Ṣugbọn nígbà tí Reubẹni gbọ́, ó gbà á kalẹ̀ lọ́wọ́ wọn, ó ní, “Ẹ má jẹ́ kí á pa á. Ẹ má ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, jíjù ni kí ẹ jù ú sinu kànga gbígbẹ láàrin aginjù yìí, ẹ má pa á lára rárá.” Ó fẹ́ fi ọgbọ́n yọ ọ́ lọ́wọ́ wọn, kí ó lè fi í ranṣẹ sí baba wọn pada. Bí Josẹfu ti dé ọ̀dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀, wọ́n fi ipá bọ́ ẹ̀wù aláràbarà rẹ̀ lọ́rùn rẹ̀

Gẹn 37:12-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì da ẹran baba wọn lọ sí Ṣekemu. Israẹli sì wí fún Josẹfu pé, “Ṣé o mọ̀ pé, àwọn arákùnrin rẹ ń da ẹran ní Ṣekemu, wá, jẹ́ kí n rán ọ sí wọn.” Josẹfu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” O sì wí fún un pé, “Lọ wò bí àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn agbo ẹran bá wà ní àlàáfíà, kí o sì wá jíṣẹ́ fún mi.” Ó sì rán Josẹfu lọ láti Àfonífojì Hebroni. Nígbà tí Josẹfu dé Ṣekemu, Ọkùnrin kan sì rí i tí ó ń rìn kiri inú pápá, ó sì bi í pé, “Kín ni ò ń wá?” Ó sì dáhùn pé, “Àwọn arákùnrin mi ni mò ń wá, ǹjẹ́ o mọ ibi tí wọ́n wà pẹ̀lú agbo ẹran?” Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Wọ́n ti kúrò ní ìhín, mo gbọ́ tí wọ́n ń wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ sí Dotani.’ ” Josẹfu sì wá àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, ó sì rí wọn ní tòsí Dotani. Ṣùgbọ́n bí wọ́n sì ti rí i tí ń bọ̀ lókèèrè, kí ó sì tó dé ọ̀dọ̀ wọn, wọn gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á. “Alálàá ni ń bọ̀ yìí,” ni wọ́n ń wí fún ara wọn. “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á. Kí a sì ju òkú rẹ̀ sínú kòtò, a ó sì wí pé, ẹranko búburú ni ó pa á, kí a máa wo ọ̀nà tí àlá rẹ̀ yóò gbà ṣẹ.” Nígbà tí Reubeni gbọ́ èyí, ó gbìyànjú láti gbà á sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn, ó sì wí pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a gba ẹ̀mí rẹ̀, Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹ má ṣe fọwọ́ kàn án, ẹ kúkú jù ú sínú kòtò láààyè nínú aginjù níbí.” Reubeni sọ èyí, kí ó ba à le gbà á kúrò lọ́wọ́ wọn, kí ó sì dá a padà lọ fún baba rẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n bọ́ ẹ̀wù rẹ̀—Ẹ̀wù ọlọ́nà, aláràbarà tí ó wọ̀