Gẹn 37:1-4
Gẹn 37:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
JAKOBU si joko ni ilẹ ti baba rẹ̀ ti ṣe atipo, ani ilẹ Kenaani. Wọnyi ni iran Jakobu. Nigbati Josefu di ẹni ọdún mẹtadilogun, o nṣọ́ agbo-ẹran pẹlu awọn arakunrin rẹ̀; ọmọde na si wà pẹlu awọn ọmọ Bilha, ati pẹlu awọn ọmọ Silpa, awọn aya baba rẹ̀; Josefu si mú ihin buburu wọn wá irò fun baba wọn. Israeli si fẹ́ Josefu jù gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ lọ, nitori ti iṣe ọmọ ogbó rẹ̀; o si dá ẹ̀wu alarabara aṣọ fun u. Nigbati awọn arakunrin rẹ̀ ri pe baba wọn fẹ́ ẹ jù gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ lọ, nwọn korira rẹ̀, nwọn kò si le sọ̀rọ si i li alafia.
Gẹn 37:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Jakọbu ń gbé ilẹ̀ Kenaani, níbi tí àwọn baba rẹ̀ ti ṣe àtìpó. Àkọsílẹ̀ ìran Jakọbu nìyí: Josẹfu jẹ́ ọmọ ọdún mẹtadinlogun ó sì ń bá àwọn arakunrin rẹ̀ tọ́jú agbo ẹran ó wà lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Biliha ati àwọn ọmọ Silipa, àwọn aya baba rẹ̀. Josẹfu a sì máa sọ gbogbo àṣìṣe àwọn arakunrin rẹ̀ fún baba wọn. Israẹli fẹ́ràn Josẹfu ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù lọ, nítorí pé ó ti di arúgbó kí ó tó bí i, nítorí náà ó dá ẹ̀wù aláràbarà kan fún un. Nígbà tí àwọn arakunrin rẹ̀ yòókù rí i pé baba wọn fẹ́ràn Josẹfu ju àwọn lọ, wọ́n kórìíra rẹ̀, wọn kì í sì fi sùúrù bá a sọ̀rọ̀.
Gẹn 37:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jakọbu sì gbé ilẹ̀ Kenaani ní ibi ti baba rẹ̀ ti gbé. Èyí ni àwọn ìtàn Jakọbu. Nígbà tí Josẹfu di ọmọ ọdún mẹ́tà-dínlógún (17), ó ń ṣọ́ agbo ẹran pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Biliha àti Silipa aya baba rẹ̀ Josẹfu sì ń ròyìn àwọn aburú tí wọ́n ń ṣe fún baba wọn. Israẹli sì fẹ́ràn Josẹfu ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ tókù lọ, nítorí ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ni ó bí i. O sì dá aṣọ aláràbarà tí ó kún fún onírúurú ọnà lára fún un. Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ rí i pé baba àwọn fẹ́ràn rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ, wọ́n kórìíra rẹ̀, wọ́n sì ń fi ẹ̀tanú bá a gbé, kò sì sí àlàáfíà láàrín wọn.