Gẹn 36:31-43
Gẹn 36:31-43 Bibeli Mimọ (YBCV)
Wọnyi si li awọn ọba ti o jẹ ni ilẹ Edomu, ki ọba kan ki o to jọba lori awọn ọmọ Israeli. Bela ti iṣe ọmọ Beori si jọba ni Edomu: orukọ ilu rẹ̀ a si ma jẹ́ Dinhaba. Bela si kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra si jọba ni ipò rẹ̀. Jobabu si kú, Huṣamu ti ilẹ Temani si jọba ni ipò rẹ̀. Huṣamu si kú, Hadadi ọmọ Bedadi, ẹniti o kọlù Midiani ni igbẹ́ Moabu si jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ si ni Afiti. Hadadi si kú, Samla ti Masreka si jọba ni ipò rẹ̀. Samla si kú, Ṣaulu ti Rehobotu leti odò nì si jọba ni ipò rẹ̀. Ṣaulu si kú, Baal-hanani ọmọ Akbori si jọba ni ipò rẹ̀. Baal-hanani ọmọ Akbori si kú, Hadari si jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ si ni Pau; Mehetabeli si li orukọ aya rẹ̀, ọmọbinrin Metredi, ọmọbinrin Mesahabu. Wọnyi si li orukọ awọn olori ti o ti ọdọ Esau wá, gẹgẹ bi idile wọn, nipa ipò wọn, nipa orukọ wọn; Timna olori, Alfa olori, Jeteti olori; Aholibama olori, Ela olori, Pinoni olori; Kenasi olori, Temani olori, Mibsari olori; Magdieli olori, Iramu olori: wọnyi li awọn olori Edomu, nipa itẹ̀dó wọn ni ilẹ iní wọn: eyi ni Esau, baba awọn ara Edomu.
Gẹn 36:31-43 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọba tí wọ́n jẹ ní ilẹ̀ Edomu kí ó tó di pé ẹnikẹ́ni jọba ní ilẹ̀ Israẹli nìwọ̀nyí: Bela, ọmọ Beori jọba ní Edomu, orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba. Nígbà tí Bela kú, Jobabu, ọmọ Sera, ará Bosira gorí oyè. Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu ti ilẹ̀ Temani, gorí oyè. Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi, ọmọ Bedadi, tí ó ṣẹgun Midiani, ní ilẹ̀ Moabu gorí oyè, orúkọ ìlú tirẹ̀ ni Afiti. Nígbà tí Hadadi kú, Samila ti Masireka gorí oyè. Nígbà tí Samila kú, Ṣaulu ará Rehoboti lẹ́bàá odò Yufurate gorí oyè. Nígbà tí Ṣaulu kú, Baali Hanani, ọmọ Akibori gorí oyè. Nígbà tí Baali Hanani ọmọ Akibori kú, Hadadi gorí oyè, orúkọ ìlú tirẹ̀ ni Pau, orúkọ aya rẹ̀ ni Mehetabeli, ọmọ Matiredi, ọmọbinrin Mesahabu. Orúkọ àwọn ìjòyè tí wọ́n ṣẹ̀ lára Esau nìwọ̀nyí, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn ati ìlú tí olukuluku ti jọba: Timna, Alfa, Jeteti, Oholibama, Ela, Pinoni, Kenasi, Temani, Mibisari, Magidieli ati Iramu. Àwọn ni ìjòyè ní Edomu, gẹ́gẹ́ bí ìlú wọn ní ilẹ̀ ìní wọn, Esau tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Edomu sì ni baba àwọn ará Edomu.
Gẹn 36:31-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn wọ̀nyí ni ọba tí ó jẹ ní Edomu kí ó tó di pé ọba kankan jẹ lórí Israẹli: Bela ọmọ Beori jẹ ní Edomu. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba. Nígbà tí Bela kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu láti ilẹ̀ Temani sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi ọmọ Bedadi tí ó kọlu Midiani ní ìgbẹ́ Moabu, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti. Nígbà tí Hadadi sì kú, Samla láti Masreka, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Samla sì kú, Saulu ti Rehoboti, létí odò sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Nígbà tí Saulu kú, Baali-Hanani ọmọ Akbori jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Nígbà tí Baali-Hanani ọmọ Akbori kú, Hadadi ni ó jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Pau, orúkọ ìyàwó sì ni Mehetabeeli ọmọbìnrin Matiredi, ọmọbìnrin Mesahabu. Àwọn wọ̀nyí ni orúkọ àwọn baálẹ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Esau jáde wá, ní orúkọ ìdílé wọn, bí ìpínlẹ̀ wọn ti rí: baálẹ̀ Timna, baálẹ̀ Alfa, baálẹ̀ Jeteti. baálẹ̀ Oholibama, baálẹ̀ Ela, baálẹ̀ Pinoni, baálẹ̀ Kenasi, baálẹ̀ Temani, baálẹ̀ Mibsari, Magdieli, àti Iramu. Àwọn wọ̀nyí ni baálẹ̀ Edomu, gẹ́gẹ́ bí wọn ti tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí wọ́n gbà.