Gẹn 36:1-8
Gẹn 36:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
WỌNYI si ni iran Esau, ẹniti iṣe Edomu. Esau fẹ́ awọn aya rẹ̀ ninu awọn ọmọbinrin Kenaani; Ada, ọmọbinrin Eloni, enia Hitti, ati Aholibama, ọmọbinrin Ana, ọmọbinrin Sibeoni, ara Hiffi; Ati Baṣemati, ọmọbinrin Iṣmaeli, arabinrin Nebajotu. Ada si bí Elifasi fun Esau; Baṣemati si bí Reueli; Aholibama si bí Jeuṣi, ati Jaalamu, ati Kora: awọn wọnyi li ọmọkunrin Esau, ti a bí fun u ni ilẹ Kenaani. Esau si mú awọn aya rẹ̀, ati awọn ọmọkunrin rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀, ati gbogbo awọn enia ile rẹ̀, ati ẹran rẹ̀, ati gbogbo ohun-ọ̀sin, ati ohun iní gbogbo ti o ní ni ilẹ Kenaani; o si lọ si ilẹ kan kuro niwaju Jakobu arakunrin rẹ̀. Nitori ti ọrọ̀ wọn pọ̀ jù ki nwọn ki o gbé pọ̀ lọ; ilẹ ti nwọn si ṣe atipo si kò le gbà wọn, nitori ohun-ọ̀sin wọn. Bẹ̃ni Esau tẹ̀dó li oke Seiri: Esau ni Edomu.
Gẹn 36:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Àkọsílẹ̀ ìran Esau, tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Edomu nìyí: Ninu àwọn ọmọbinrin Kenaani ni Esau ti fẹ́ aya, ekinni ń jẹ́ Ada, ọmọ Eloni ará Hiti, ekeji ń jẹ́ Oholibama, ọmọ Ana tí baba rẹ̀ ń jẹ́ Sibeoni, ará Hifi. Ẹkẹta ń jẹ́ Basemati ọmọ Iṣimaeli, arabinrin Nebaiotu. Ada bí Elifasi fún Esau, Basemati bí Reueli. Oholibama bí Jeuṣi, Jalamu ati Kora. Àwọn ni ọmọ Esau, tí àwọn aya rẹ̀ bí fún un ní ilẹ̀ Kenaani. Nígbà tí ó ṣe, Esau kó àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn mààlúù rẹ̀, àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀, ati gbogbo ohun ìní rẹ̀ tí ó ti kójọ ní ilẹ̀ Kenaani, ó kó kúrò ní ilẹ̀ Kenaani lọ́dọ̀ Jakọbu, arakunrin rẹ̀. Ìdí ni pé ọrọ̀ wọn ti pọ̀ ju kí wọ́n jọ máa gbé pọ̀ lọ, ilẹ̀ tí wọ́n sì ti ń ṣe àtìpó kò gbà wọ́n mọ́, nítorí pé wọ́n ní ẹran ọ̀sìn tí ó pọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Esau ṣe di ẹni tí ń gbé orí òkè Seiri. Esau kan náà ni ń jẹ́ Edomu.
Gẹn 36:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ̀nyí ni ìran Esau, ẹni tí a ń pè ní Edomu. Nínú àwọn ọmọbìnrin Kenaani ni Esau ti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀: Adah ọmọbìnrin Eloni ará Hiti àti Oholibama, ọmọbìnrin Ana, ọmọ ọmọ Sibeoni ará Hifi. Ó sì tún fẹ́ Basemati ọmọ Iṣmaeli arábìnrin Nebaioti. Adah bí Elifasi fún Esau, Basemati sì bí Reueli, Oholibama pẹ̀lú sì bí Jeuṣi, Jalamu, àti Kora. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Esau bí ní Kenaani. Esau sì mú àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ àti àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn àti gbogbo ohun ìní mìíràn tí ó ní, ni Kenaani, ó sì kó lọ sí ilẹ̀ mìíràn, jìnà sí ibi tí Jakọbu arákùnrin rẹ̀ wà. Ohun ìní wọn pọ̀ ju èyí tí àwọn méjèèjì lè máa gbé ní ojú kan lọ. Ilẹ̀ tí wọ́n wà kò le gba àwọn méjèèjì nítorí àwọn ohun ọ̀sìn wọn. Báyìí ni Esau tí a tún mọ̀ sí Edomu tẹ̀dó sí àwọn orílẹ̀-èdè olókè tí Seiri.