Gẹn 31:7-8,13
Gẹn 31:7-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Baba nyin si ti tàn mi jẹ, o si pa ọ̀ya mi dà nigba mẹwa: ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ ki o pa mi lara. Bi o ba si wi bayi pe, Awọn abilà ni yio ṣe ọ̀ya rẹ; gbogbo awọn ẹran a si bí abilà: bi o ba si wi bayi, Awọn oni-tototó ni yio ṣe ọ̀ya rẹ; gbogbo awọn ẹran a si bí oni-tototó.
Gẹn 31:13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi li Ọlọrun Beteli, nibiti iwọ gbé ta oróro si ọwọ̀n, nibiti iwọ gbè jẹ́ ẹjẹ́ fun mi: dide nisisiyi, jade kuro ni ilẹ yi, ki o si pada lọ si ilẹ ti a bi ọ.
Gẹn 31:7-8 Yoruba Bible (YCE)
sibẹ, baba yín rẹ́ mi jẹ, ó sì yí owó ọ̀yà mi pada nígbà mẹ́wàá, ṣugbọn Ọlọrun kò gbà fún un láti pa mí lára. Bí ó bá wí pé àwọn ẹran tí ó ní funfun tóótòòtóó ni yóo jẹ́ owó ọ̀yà mi, gbogbo ẹran inú agbo a sì bí onífunfun tóótòòtóó. Bí ó bá sì wí pé, àwọn ẹran tí ó bá ní àwọ̀ tí ó dàbí adíkálà ni yóo jẹ́ tèmi, gbogbo ẹran inú agbo a sì bí ọmọ tí àwọ̀ wọn dàbí adíkálà.
JẸNẸSISI 31:13 Yoruba Bible (YCE)
Èmi ni Ọlọrun Bẹtẹli, níbi tí o ti ta òróró sórí òkúta tí o sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún mi. Dìde nisinsinyii, kí o jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí, kí o sì pada sí ilẹ̀ tí wọ́n gbé bí ọ.’ ”
Gẹn 31:7-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Síbẹ̀síbẹ̀ baba yín ti rẹ́ mi jẹ ní ẹ̀ẹ̀mẹwàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó sì ti yí owó iṣẹ́ mi padà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò jẹ́ kí ó le è pa mi lára. Tí ó bá wí pé, ‘Àwọn ẹran onílà ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ rẹ,’ nígbà náà ni gbogbo àwọn ẹran ń bí onílà; bí ó bá sì wí pé, ‘Àwọn ẹran onítótòtó ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ rẹ’ nígbà náà ni gbogbo ẹran ń bi onítótòtó.