Gẹn 3:8-9
Gẹn 3:8-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun, o nrìn ninu ọgbà ni itura ọjọ́: Adamu ati aya rẹ̀ si fi ara wọn pamọ́ kuro niwaju OLUWA Ọlọrun lãrin igi ọgbà. OLUWA Ọlọrun si kọ si Adamu, o si wi fun u pe, Nibo ni iwọ wà?
Pín
Kà Gẹn 3Gẹn 3:8-9 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbúròó OLUWA Ọlọrun tí ń rìn ninu ọgbà. Wọ́n bá sá pamọ́ sí ààrin àwọn igi ọgbà. Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun pe ọkunrin náà, ó bi í pé, “Níbo ni o wà?”
Pín
Kà Gẹn 3Gẹn 3:8-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ gbọ́ ìró OLúWA Ọlọ́run bí ó ti ń rìn nínú ọgbà, nígbà tí ojú ọjọ́ tura, wọ́n sì fi ara pamọ́ kúrò níwájú OLúWA Ọlọ́run sí àárín àwọn igi inú ọgbà. Ṣùgbọ́n OLúWA Ọlọ́run ké pe ọkùnrin náà pé, “Níbo ni ìwọ wà?”
Pín
Kà Gẹn 3