Gẹn 3:1-3
Gẹn 3:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
EJÒ sa ṣe alarekereke jù ẹranko igbẹ iyoku lọ ti OLUWA Ọlọrun ti dá. O si wi fun obinrin na pe, õtọ li Ọlọrun wipe, Ẹnyin kò gbọdọ jẹ gbogbo eso igi ọgbà? Obinrin na si wi fun ejò na pe, Awa a ma jẹ ninu eso igi ọgbà: Ṣugbọn ninu eso igi nì ti o wà lãrin ọgbà Ọlọrun ti wipe, Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fọwọkàn a, ki ẹnyin ki o má ba kú.
Gẹn 3:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Ejò jẹ́ alárèékérekè ju gbogbo ẹranko tí OLUWA Ọlọrun dá lọ. Ejò bi obinrin náà pé, “Ngbọ́! Ṣé nítòótọ́ ni Ọlọrun sọ pé ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso àwọn igi ọgbà yìí?” Obinrin náà dá a lóhùn, ó ní: “A lè jẹ ninu èso àwọn igi tí wọ́n wà ninu ọgbà, àfi igi tí ó wà láàrin ọgbà nìkan ni Ọlọrun ní a kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso rẹ̀, a kò tilẹ̀ gbọdọ̀ fọwọ́ kàn án, ati pé ọjọ́ tí a bá fọwọ́ kàn án ni a óo kú.”
Gẹn 3:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ejò sá à ṣe alárékérekè ju àwọn ẹranko igbó yòókù tí OLúWA Ọlọ́run dá lọ. Ó sọ fún obìnrin náà pé, “Ǹjẹ́ òtítọ́ ha ni Ọlọ́run wí pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ èso èyíkéyìí lára àwọn igi tí ó wà nínú ọgbà’?” Obìnrin náà dá ejò lóhùn pé, “Àwa lè jẹ lára àwọn èso igi tí ó wà nínú ọgbà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ lára èso igi tí ó wà láàrín ọgbà, ẹ kò sì gbọdọ̀ fi ọwọ́ kàn án, bí ẹ̀yin bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin yóò kùú.’ ”