Gẹn 27:1-20

Gẹn 27:1-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe, ti Isaaki gbó, ti oju rẹ̀ si nṣe bàibai, tobẹ̃ ti kò le riran, o pè Esau, ọmọ rẹ̀ akọ́bi, o si wi fun u pe, Ọmọ mi: on si dá a li ohùn pe, Emi niyi. O si wipe, Wò o na, emi di arugbo, emi kò si mọ̀ ọjọ́ ikú mi; Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, mu ohun ọdẹ rẹ, apó rẹ, ati ọrun rẹ, ki o si jade lọ si igbẹ́ ki o si pa ẹran-igbẹ́ fun mi wá: Ki o si sè ẹran adidùn fun mi, bi irú eyiti mo fẹ́, ki o si gbé e tọ̀ mi wá, ki emi ki o jẹ: ki ọkàn mi ki o súre fun ọ ki emi to kú. Rebeka si gbọ́ nigbati Isaaki nwi fun Esau, ọmọ rẹ̀. Esau si lọ si igbẹ́ lọ iṣọdẹ, lati pa ẹran-igbẹ́ wá. Rebeka si wi fun Jakobu ọmọ rẹ̀ pe, Wò o, mo gbọ́ baba rẹ wi fun Esau arakunrin rẹ pe, Mu ẹran-igbẹ́ fun mi wá, ki o si sè ẹran adidùn fun mi, ki emi ki o jẹ, ki emi ki o sure fun ọ niwaju OLUWA ṣaju ikú mi. Njẹ nisisiyi, ọmọ mi, gbọ́ ohùn mi, gẹgẹ bi emi o ti paṣẹ fun ọ. Lọ nisisiyi sinu agbo-ẹran, ki o si mu ọmọ ewurẹ meji daradara fun mi lati ibẹ̀ wá: emi o si sè wọn li ẹran adidùn fun baba rẹ, bi irú eyiti o fẹ́: Iwọ o si gbé e tọ̀ baba rẹ lọ, ki o le jẹ, ki o le súre fun ọ, ki on to kú. Jakobu si wi fun Rebeka iya rẹ̀ pe, Kiyesi i, enia onirun ni Esau arakunrin mi, alara ọbọrọ́ si li emi: Bọya baba mi yio fọwọbà mi, emi o si dabi ẹlẹ̀tan fun u; emi o si mu egún wá si ori mi ki yio ṣe ibukún. Iya rẹ̀ si wi fun u pe, lori mi ni ki egún rẹ wà, ọmọ mi: sá gbọ́ ohùn mi, ki o si lọ mu wọn fun mi wá. O si lọ, o mu wọn, o si fà wọn tọ̀ iya rẹ̀ wá: iya rẹ̀ si sè ẹran adidùn; bi irú eyiti baba rẹ̀ fẹ́. Rebeka si mu ãyo aṣọ Esau, ọmọ rẹ̀ ẹgbọ́n, ti o wà lọdọ rẹ̀ ni ile, o si fi wọn wọ̀ Jakobu, ọmọ rẹ̀ aburo: O si fi awọ awọn ọmọ ewurẹ wọnni bò o li ọwọ́, ati si ọbọrọ́ ọrùn rẹ̀: O si fi ẹran adidùn na, ati àkara ti o ti pèse, le Jakobu, ọmọ rẹ̀, lọwọ. O si tọ̀ baba rẹ̀ wá, o wipe, Baba mi: on si wipe, Emi niyi; iwọ tani nì ọmọ mi? Jakobu si wi fun baba rẹ̀ pe, Emi Esau akọ́bi rẹ ni; emi ti ṣe gẹgẹ bi o ti sọ fun mi, dide joko, emi bẹ̀ ọ, ki o si jẹ ninu ẹran-igbẹ́ mi, ki ọkàn rẹ le súre fun mi. Isaaki si wi fun ọmọ rẹ̀ pe, Ẽti ri ti iwọ fi tete ri i bẹ̃, ọmọ mi? on si wipe, Nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ mu u tọ̀ mi wá ni.

Gẹn 27:1-20 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí Isaaki di arúgbó, tí ojú rẹ̀ sì di bàìbàì tóbẹ́ẹ̀ tí kò le ríran mọ́, ó pe Esau àkọ́bí rẹ̀, ó ní, “Ọmọ mi.” Esau sì dá a lóhùn pé, “Èmi nìyí.” Isaaki wí pé, “Ṣé o rí i báyìí pé mo ti darúgbó, n kò sì mọ ọjọ́ ikú mi. Kó àwọn ohun ọdẹ rẹ: ọrun ati ọfà rẹ, lọ sí ìgbẹ́, kí o sì pa ẹran wá fún mi. Lẹ́yìn náà, se irú oúnjẹ aládùn tí mo fẹ́ràn fún mi, kí n jẹ ẹ́, kí ọkàn mi lè súre fún ọ kí n tó kú.” Ní gbogbo ìgbà tí Isaaki ń bá Esau ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀, Rebeka ń gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ. Nítorí náà nígbà tí Esau jáde lọ sinu ìgbẹ́, Rebeka pe Jakọbu ọmọ rẹ̀, ó sọ fún un, ó ní, “Mo gbọ́ tí baba yín ń bá Esau ẹ̀gbọ́n rẹ sọ̀rọ̀, pé kí ó lọ pa ẹran wá fún òun, kí ó sì se oúnjẹ aládùn kí òun lè jẹ ẹ́, kí òun sì súre fún un níwájú OLUWA kí òun tó kú. Nítorí náà, ọmọ mi, fetí sílẹ̀ kí o sì ṣe ohun tí n óo sọ fún ọ. Lọ sinu agbo ẹran rẹ, kí o sì mú ọmọ ewúrẹ́ meji tí ó lọ́ràá wá, kí n fi se irú oúnjẹ aládùn tí baba yín fẹ́ràn fún un, o óo sì lọ gbé e fún baba yín, kí ó jẹ ẹ́, kí ó baà lè súre fún ọ, kí ó tó kú.” Ṣugbọn Jakọbu dá Rebeka ìyá rẹ̀ lóhùn, ó ní, “Onírun lára ni Esau, ẹ̀gbọ́n mi, n kò sì ní irun lára. Ó ṣeéṣe kí baba mi fi ọwọ́ pa mí lára, yóo wá dàbí ẹni pé mo wá fi ṣe ẹlẹ́yà. Nípa bẹ́ẹ̀ n óo fa ègún sórí ara mi dípò ìre.” Ìyá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Kí ègún náà wá sí orí mi, ọmọ mi, ṣá gba ohun tí mo wí, kí o sì lọ mú àwọn ewúrẹ́ náà wá.” Jakọbu bá lọ mú wọn wá fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì se irú oúnjẹ aládùn tí baba wọn fẹ́ràn. Lẹ́yìn náà Rebeka mú aṣọ Esau, àkọ́bí rẹ̀, tí ó dára jùlọ, tí ó wà nílé lọ́dọ̀ rẹ̀, ó wọ̀ ọ́ fún Jakọbu ọmọ rẹ̀. Ó mú awọ ewúrẹ́ tí ó pa, ó fi bo ọwọ́ Jakọbu ati ibi tí ó ń dán ní ọrùn rẹ̀, ó sì gbé oúnjẹ aládùn tí ó sè ati àkàrà tí ó tọ́jú fún Jakọbu ọmọ rẹ̀. Ni Jakọbu bá tọ baba rẹ̀ lọ, ó pè é, ó ní, “Baba mi,” Baba rẹ̀ bá dá a lóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi, ìwọ ta ni?” Jakọbu dá baba rẹ̀ lóhùn, ó ní, “Èmi Esau, àkọ́bí rẹ ni, mo ti ṣe bí o ti wí, dìde jókòó, kí o sì jẹ ninu ẹran ìgbẹ́ tí mo pa, kí o lè súre fún mi.” Ṣugbọn Isaaki bi í léèrè pé, “O ti ṣe é tí o fi rí ẹran pa kíákíá bẹ́ẹ̀ ọmọ mi?” Jakọbu dáhùn pé “OLUWA Ọlọrun rẹ ni ó ṣe ọ̀nà mi ní rere.”

Gẹn 27:1-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà ti Isaaki di arúgbó, ojú rẹ̀ sì ti di bàìbàì tó bẹ́ẹ̀ tí kò le ríran. Ó pe Esau àkọ́bí rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Ọmọ mi.” Esau sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Isaaki sì wí pé, “Nísinsin yìí mo di arúgbó, èmi kò sì mọ ọjọ́ tí èmi yóò kú. Nítorí náà, mú ohun èlò ọdẹ rẹ—apó àti ọrún—nísinsin yìí kí o sì lọ pa ẹran wá fún mi nínú igbó. Kí o sì ṣe ẹran àdídùn fún mi, irú èyí tí mo fẹ́ràn, kí o gbe wá fún mi kí n jẹ, kí n sì súre fún ọ kí n tó kú.” Ṣùgbọ́n Rebeka ń fetí léko gbọ́ nígbà tí Isaaki ń bá Esau ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nítorí náà, nígbà ti Esau ti ṣe ọdẹ lọ sínú igbó, Rebeka sọ fún Jakọbu ọmọ rẹ̀ pé, “Wò ó, mo gbọ́ tí baba rẹ ń wí fún Esau ẹ̀gbọ́n rẹ pé, ‘Pa ẹran fún mi wá, kí o sì ṣe oúnjẹ àdídùn fún mi láti jẹ, kí n ba à le súre fún ọ níwájú OLúWA kí èmi tó kú.’ Nísinsin yìí ọmọ mi, gbọ́ tèmi, kí o sì ṣe ohun tí èmi yóò wí fún ọ: Lọ sínú agbo ẹran, kí o sì mú ọmọ ewúrẹ́ méjì, kí ó lè ṣe oúnjẹ àdídùn fún baba rẹ, irú èyí tí ó fẹ́ràn dáradára. Ìwọ yóò sì gbé e tọ baba rẹ lọ, kí òun ba à lè jẹ ẹ́, kí ó sì súre fún ọ, kí ó tó kú.” Jakọbu sì wí fún Rebeka ìyá rẹ̀ pé, “Ṣùgbọ́n Esau ẹ̀gbọ́n mi jẹ́ ènìyàn onírun lára, bẹ́ẹ̀ alára ọ̀bọ̀rọ́ sì ni èmi, Bí baba mi bá fọwọ́ kàn mi ńkọ́? Èmi yóò jọ ẹlẹ́tàn lójú rẹ̀, dípò kí ó súre fún mi, èmi yóò sì mú ègún wá sórí ara mi.” Ìyá rẹ̀ wá wí fun un pé, “Ọmọ mi jẹ́ kí ègún náà wá sórí mi, sá à ṣe ohun tí mo wí, kí o sì mú wọn wá fún mi.” Jakọbu sì ṣe ohun gbogbo tí ìyá rẹ̀ wí fun un, Rebeka sì ṣe oúnjẹ àdídùn náà, irú èyí tí Isaaki fẹ́ràn. Nígbà náà ni Rebeka mú èyí tí ó dára jù nínú aṣọ Esau ọmọ rẹ̀ àgbà tí ó wà nínú ilé Rebeka, ó sì fi wọ Jakọbu ọmọ rẹ̀ àbúrò. Ó sì fi awọ ewúrẹ́ wọ̀n-ọn-nì bo ọwọ́ àti ibi tí ọ̀bọ̀rọ́ ọrùn. Nígbà náà ni ó gbé ẹran dídùn náà àti oúnjẹ tí ó ti sè lé Jakọbu ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. Jakọbu wọlé lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi.” Baba rẹ sì dáhùn pé, “Èmi nìyí, ìwọ ta ni, ọmọ mi?” Jakọbu sì fèsì pé, “Èmi ni Esau àkọ́bí rẹ, èmi ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti sọ fún mi, jọ̀wọ́ dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran igbó mi tí mo ti sè, kí o ba à le súre fún mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.” Isaaki tún béèrè pé, “Ọmọ mi, báwo ni ó ṣe tètè yá ọ bẹ́ẹ̀?” Jakọbu sì tún dáhùn pé, “OLúWA Ọlọ́run rẹ ló fún mi pa.”