Gẹn 22:1-5
Gẹn 22:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe lẹhin nkan wọnyi ni Ọlọrun dan Abrahamu wò, o si wi fun u pe, Abrahamu: on si dahùn pe, Emi niyi. O si wi fun u pe, Mu ọmọ rẹ nisisiyi, Isaaki, ọmọ rẹ na kanṣoṣo, ti iwọ fẹ́, ki iwọ ki o si lọ si ilẹ Moria; ki o si fi i rubọ sisun nibẹ̀ lori ọkan ninu oke ti emi o sọ fun ọ. Abrahamu si dide ni kutukutu owurọ̀, o si dì kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ ni gãrì, o si mu meji ninu awọn ọdọmọkunrin rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati Isaaki, ọmọ rẹ̀, o si là igi fun ẹbọ sisun na, o si dide, o si lọ si ibi ti Ọlọrun sọ fun u. Ni ijọ́ kẹta Abrahamu si gbé oju rẹ̀ soke, o ri ibẹ̀ na li okere. Abrahamu si wi fun awọn ọdọmọkunrin rẹ̀, pe, Ẹnyin joko nihin pẹlu kẹtẹkẹtẹ; ati emi ati ọmọ yi yio lọ si ọhùn ni, a o si gbadura, a o si tun pada tọ̀ nyin wá.
Gẹn 22:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn nǹkan wọnyi, Ọlọrun dán Abrahamu wò, ó ní, “Abrahamu!” Abrahamu dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Ọlọrun ní, “Mú Isaaki ọmọ rẹ kan ṣoṣo tí o fẹ́ràn, kí o lọ sí ilẹ̀ Moraya, kí o sì fi ọmọ náà rú ẹbọ sísun lórí ọ̀kan ninu àwọn òkè tí n óo júwe fún ọ.” Abrahamu bá dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó mú meji ninu àwọn ọdọmọkunrin ilé rẹ̀, ati Isaaki ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. Ó gé igi fún ẹbọ sísun, lẹ́yìn náà wọ́n gbéra, wọ́n lọ sí ibi tí Ọlọrun ti júwe fún Abrahamu. Ní ọjọ́ kẹta, bí Abrahamu ti wo ọ̀kánkán, ó rí ibi tí Ọlọrun júwe fún un ní òkèèrè. Abrahamu bá sọ fún àwọn ọdọmọkunrin tí wọ́n tẹ̀lé e, ó ní, “Ẹ dúró ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ níhìn-ín, èmi ati ọmọ yìí yóo rìn siwaju díẹ̀, láti lọ sin Ọlọ́run, a óo sì pada wá bá yín.”
Gẹn 22:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ó ṣe, Ọlọ́run dán Abrahamu wò, ó pè é, ó sì wí pé, “Abrahamu.” Abrahamu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Ọlọ́run sì wí pé, “Mú ọmọ rẹ, àní Isaaki ọmọ rẹ kan ṣoṣo nì, tí ìwọ fẹ́ràn, lọ sí ilẹ̀ Moriah, kí o sì fi rú ẹbọ sísun níbẹ̀ lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè tí èmi yóò sọ fún ọ.” Abrahamu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì mú méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Isaaki ọmọ rẹ̀, ó sì ṣẹ́ igi fún ẹbọ sísun, ó sì gbéra lọ sí ibi tí Ọlọ́run ti sọ fún un. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹta, Abrahamu gbé ojú sókè, ó sì rí ibi tí ó ń lọ ní òkèrè, Abrahamu sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin, ẹ dúró níhìn-ín pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, èmi àti ọmọ yìí yóò lọ sí ohunkóhun láti sin Ọlọ́run, a ó sì tún padà wá bá a yín.”