Gẹn 2:4-8
Gẹn 2:4-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Itan ọrun on aiye ni wọnyi nigbati a dá wọn, li ọjọ́ ti OLUWA Ọlọrun dá aiye on ọrun. Ati olukuluku igi igbẹ ki o to wà ni ilẹ, ati olukuluku eweko igbẹ ki nwọn ki o to hù: OLUWA Ọlọrun kò sa ti rọ̀jo si ilẹ, kò si sí enia kan lati ro ilẹ. Ṣugbọn ikũku a ti ilẹ wá, a si ma rin oju ilẹ gbogbo. OLUWA Ọlọrun si fi erupẹ ilẹ mọ enia; o si mí ẹmí ìye si ihò imu rẹ̀; enia si di alãye ọkàn. OLUWA Ọlọrun si gbìn ọgbà kan niha ìla-õrùn ni Edeni; nibẹ̀ li o si fi ọkunrin na ti o ti mọ si.
Gẹn 2:4-8 Yoruba Bible (YCE)
Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe dá ọ̀run ati ayé. Nígbà tí OLUWA Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé, kò tíì sí ohun ọ̀gbìn kankan lórí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ewéko kankan kò tíì hù jáde nítorí pé OLUWA Ọlọrun kò tíì rọ òjò sórí ilẹ̀, kò sì tíì sí eniyan láyé tí yóo máa ro ilẹ̀. Ṣugbọn omi kan a máa ru jáde láti inú ilẹ̀ láti mú kí gbogbo ilẹ̀ rin. Nígbà náà ni OLUWA Ọlọrun bù ninu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ eniyan. Ó mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, eniyan sì di ẹ̀dá alààyè. OLUWA Ọlọrun ṣe ọgbà kan sí Edẹni, ní ìhà ìlà oòrùn, ó fi eniyan tí ó mọ sinu rẹ̀.
Gẹn 2:4-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èyí ni ìtàn bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn ọ̀run àti ayé nígbà tí ó dá wọn. Nígbà tí OLúWA Ọlọ́run dá ayé àti àwọn ọ̀run. Kò sí igi igbó kan ní orí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ewéko igbó kan tí ó tí ì hù jáde ní ilẹ̀, nítorí OLúWA Ọlọ́run kò tí ì rọ̀jò sórí ilẹ̀, kò sì sí ènìyàn láti ro ilẹ̀. Ṣùgbọ́n ìsun omi ń jáde láti ilẹ̀, ó sì ń bu omi rin gbogbo ilẹ̀. OLúWA Ọlọ́run sì fi erùpẹ̀ ilẹ̀ mọ ènìyàn, ó si mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, ènìyàn sì di alààyè ọkàn. OLúWA Ọlọ́run sì gbin ọgbà kan sí Edeni ní ìhà ìlà-oòrùn, níbẹ̀ ni ó fi ọkùnrin náà tí ó ti dá sí.