Gẹn 2:18-25
Gẹn 2:18-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA Ọlọrun si wipe, kò dara ki ọkunrin na ki o nikan ma gbé; emi o ṣe oluranlọwọ ti o dabi rẹ̀ fun u. Lati inu ilẹ li OLUWA Ọlọrun si ti dá ẹranko igbẹ gbogbo, ati ẹiyẹ oju-ọrun gbogbo; o si mu wọn tọ̀ Adamu wá lati wò orukọ ti yio sọ wọn; orukọkorukọ ti Adamu si sọ olukuluku ẹda alãye, on li orukọ rẹ̀. Adamu si sọ ẹran-ọ̀sin gbogbo, ati ẹiyẹ oju-ọrun, ati ẹranko igbẹ gbogbo, li orukọ; ṣugbọn fun Adamu a kò ri oluranlọwọ ti o dabi rẹ̀ fun u. OLUWA Ọlọrun si mu orun ìjika kùn Adamu, o si sùn: o si yọ ọkan ninu egungun-ìha rẹ̀, o si fi ẹran di ipò rẹ̀: OLUWA Ọlọrun si fi egungun-ìha ti o mu ni ìha ọkunrin na mọ obinrin, o si mu u tọ̀ ọkunrin na wá. Adamu si wipe, Eyiyi li egungun ninu egungun mi, ati ẹran-ara ninu ẹran-ara mi: Obinrin li a o ma pè e, nitori ti a mu u jade lati ara ọkunrin wá. Nitori na li ọkunrin yio ṣe ma fi baba on iya rẹ̀ silẹ, yio si fi ara mọ́ aya rẹ̀: nwọn o si di ara kan. Awọn mejeji si wà ni ìhoho, ati ọkunrin na ati obinrin rẹ̀, nwọn kò si tiju.
Gẹn 2:18-25 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà OLUWA Ọlọrun sọ pé, “Kò dára kí ọkunrin náà nìkan dá wà, n óo ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, tí yóo dàbí rẹ̀.” Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun bu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ gbogbo ẹranko ati gbogbo ẹyẹ. Ó kó wọn tọ ọkunrin náà wá, láti mọ orúkọ tí yóo sọ olukuluku wọn. Orúkọ tí ó sì sọ wọ́n ni wọ́n ń jẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni ọkunrin náà sọ gbogbo ẹran ọ̀sìn ati gbogbo ẹyẹ ati ẹranko ní orúkọ, ṣugbọn ninu gbogbo wọn, kò sí ọ̀kan tí ó le jẹ́ olùrànlọ́wọ́ tí ó yẹ ẹ́. Nígbà náà OLUWA Ọlọrun kun ọkunrin yìí ní oorun àsùnwọra, nígbà tí ó sùn, Ọlọrun yọ ọ̀kan ninu àwọn egungun ìhà rẹ̀, ó sì fi ẹran dípò rẹ̀. Ó fi egungun náà mọ obinrin kan, ó sì mú un tọ ọkunrin náà lọ. Ọkunrin náà bá wí pé, “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ẹni tí ó dàbí mi, ẹni tí a mú jáde láti inú egungun ati ẹran ara mi; obinrin ni yóo máa jẹ́, nítorí pé láti ara ọkunrin ni a ti mú un jáde.” Ìdí nìyí tí ọkunrin yóo ṣe fi baba ati ìyá rẹ̀ sílẹ̀, tí yóo sì faramọ́ aya rẹ̀, àwọn mejeeji yóo sì di ara kan ṣoṣo. Ọkunrin náà ati obinrin náà wà ní ìhòòhò, ojú kò sì tì wọ́n.
Gẹn 2:18-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA Ọlọ́run wí pé, “Kò dára kí ọkùnrin wà ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀ fún un.” Lẹ́yìn tí OLúWA Ọlọ́run ti dá àwọn ẹranko inú igbó àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀. Ó sì kó wọn tọ ọkùnrin náà wá láti wo orúkọ tí yóò sọ wọ́n; orúkọ tí ó sì sọ gbogbo ẹ̀dá alààyè náà ni wọ́n ń jẹ́. Gbogbo ohun ọ̀sìn, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹranko igbó ni ọkùnrin náà sọ ní orúkọ. Ṣùgbọ́n fún Adamu ni a kò rí olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀. Nígbà náà ni OLúWA Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sùn fọnfọn; nígbà tí ó sì ń sùn, Ọlọ́run yọ egungun ìhà rẹ̀ kan, ó sì fi ẹran-ara bò ó padà. OLúWA Ọlọ́run sì dá obìnrin láti inú egungun tí ó yọ ní ìhà ọkùnrin náà, Ó sì mu obìnrin náà tọ̀ ọ́ wá. Ọkùnrin náà sì wí pé, “Èyí ni egungun láti inú egungun mi àti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi; ‘obìnrin’ ni a ó máa pè é, nítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin.” Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan. Ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ sì wà ní ìhòhò, ojú kò sì tì wọ́n.