Gẹn 14:14-16
Gẹn 14:14-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati Abramu gbọ́ pe a dì arakunrin on ni igbekun, o kó awọn ọmọ ọdọ rẹ̀ ti a ti kọ́, ti a bí ni ile rẹ̀ jade, ọrindinirinwo enia o din meji, o si lepa wọn de Dani. O si pín ara rẹ̀, on, pẹlu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, si wọn li oru, o si kọlù wọn, o si lépa wọn de Hoba, ti o wà li apa òsi Damasku: O si gbà gbogbo ẹrù na pada, o si gbà Loti arakunrin rẹ̀ pada pẹlu, ati ẹrù rẹ̀, ati awọn obinrin pẹlu, ati awọn enia.
Gẹn 14:14-16 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Abramu gbọ́ pé wọ́n ti mú ìbátan òun lẹ́rú, ó kó ọọdunrun ó lé mejidinlogun (318) ninu àwọn ọkunrin tí wọ́n bí sinu ilé rẹ̀, tí ó sì ti kọ́ ní ogun jíjà, ó lépa àwọn tí wọ́n mú Lọti lẹ́rú lọ títí dé ilẹ̀ Dani. Ó pín àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí ní òru ọjọ́ náà. Òun ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ yí àwọn ọ̀tá náà po, wọ́n ṣí wọn nídìí, wọ́n sì lépa wọn títí dé ìlú Hoba ní apá ìhà àríwá Damasku. Abramu gba gbogbo ìkógun tí wọ́n kó pada, ó gba Lọti, ìbátan rẹ̀ pẹlu ati gbogbo ohun ìní rẹ̀, ati àwọn obinrin ati ọ̀pọ̀ àwọn eniyan mìíràn.
Gẹn 14:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Abramu gbọ́ wí pé, a di Lọti ní ìgbèkùn, ó kó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí a bí sí ilẹ̀ rẹ̀ tí ó sì ti kọ́ ni ogun jíjà jáde, wọ́n jẹ́ okòó-lé-lọ́ọ̀dúnrún ó dín méjì ènìyàn (318), ó sì lépa wọn títí dé Dani. Ní ọ̀gànjọ́ òru, Abramu pín àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sí méjì, ó sì kọlù wọ́n, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì lé wọn títí dé Hoba tí ó wà ní apá òsì Damasku. Gbogbo ìkógun ni ó rí gbà padà àti ọmọ arákùnrin rẹ̀, Lọti pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀, àti àwọn obìnrin pẹ̀lú àwọn ènìyàn tókù.