Gẹn 1:2-5
Gẹn 1:2-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Aiye si wà ni jũju, o si ṣofo; òkunkun si wà loju ibú: Ẹmi Ọlọrun si nràbaba loju omi. Ọlọrun si wipe, Ki imọlẹ ki o wà: imọlẹ si wà. Ọlọrun si ri imọlẹ na, pe o dara: Ọlọrun si pàla si agbedemeji imọlẹ ati òkunkun. Ọlọrun si pè imọlẹ ni Ọsán, ati òkunkun ni Oru. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kini.
Gẹn 1:2-5 Yoruba Bible (YCE)
ayé rí júujùu, ó sì ṣófo. Ibú omi bo gbogbo ayé, gbogbo rẹ̀ ṣókùnkùn biribiri, ẹ̀mí Ọlọrun sì ń rábàbà lójú omi. Ọlọrun pàṣẹ pé kí ìmọ́lẹ̀ wà, ìmọ́lẹ̀ sì wà. Ọlọrun wò ó, ó rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì yà á kúrò lára òkùnkùn. Ó sọ ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, ó sì sọ òkùnkùn ní òru. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kinni.
Gẹn 1:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ayé sì wà ní rúdurùdu, ó sì ṣófo, òkùnkùn sì wà lójú ibú omi, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń rábàbà lójú omi. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà,” ìmọ́lẹ̀ sì wà. Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì ya ìmọ́lẹ̀ náà sọ́tọ̀ kúrò lára òkùnkùn. Ọlọ́run sì pe ìmọ́lẹ̀ náà ní “Ọ̀sán” àti òkùnkùn ní “Òru.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní.