Gal 6:4-7
Gal 6:4-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ki olukuluku ki o yẹ iṣẹ ara rẹ̀ wò, nigbana ni yio si ni ohun iṣogo nipa ti ara rẹ̀ nikan, kì yio si ṣe nipa ti ọmọnikeji rẹ̀. Nitori olukuluku ni yio rù ẹrù ti ara rẹ̀. Ṣugbọn ki ẹniti a nkọ́ ninu ọ̀rọ na mã pese ohun rere gbogbo fun ẹniti nkọni. Ki a máṣe tàn nyin jẹ; a kò le gàn Ọlọrun: nitori ohunkohun ti enia ba funrugbin, on ni yio si ká.
Gal 6:4-7 Yoruba Bible (YCE)
Kí olukuluku yẹ iṣẹ́ ara rẹ̀ wò, nígbà náà yóo lè ṣògo lórí iṣẹ́ tirẹ̀, kì í ṣe pé kí ó máa fi iṣẹ́ tirẹ̀ wé ti ẹlòmíràn. Nítorí olukuluku gbọdọ̀ ru ẹrù tirẹ̀. Ẹni tí ó ń kọ́ ẹ̀kọ́ ìyìn rere gbọdọ̀ máa pín olùkọ́ rẹ̀ ninu àwọn nǹkan rere rẹ̀. Ẹ má tan ara yín jẹ: eniyan kò lè mú Ọlọrun lọ́bọ. Ohunkohun tí eniyan bá gbìn ni yóo ká.
Gal 6:4-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yẹ iṣẹ́ ara rẹ̀ wò, nígbà náà, ohun ìmú-ṣogo rẹ̀ yóò jẹ́ nínú ti ara rẹ̀ nìkan, kì yóò sì jẹ nínú ti ọmọnìkejì rẹ̀. Nítorí pé olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n kí ẹni tí a ń kọ́ nínú ọ̀rọ̀ náà máa pèsè ohun rere gbogbo fún ẹni tí ń kọ́ni. Kí a má ṣe tàn yín jẹ; a kò lè gan Ọlọ́run: nítorí ohunkóhun tí ènìyàn bá fúnrúgbìn, òhun ni yóò sì ká.