Gal 6:2-4
Gal 6:2-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ mã rù ẹrù ọmọnikeji nyin, ki ẹ si fi bẹ̃ mu ofin Kristi ṣẹ. Nitori bi enia kan ba nrò ara rẹ̀ si ẹnikan, nigbati kò jẹ nkan, o ntàn ara rẹ̀ jẹ. Ṣugbọn ki olukuluku ki o yẹ iṣẹ ara rẹ̀ wò, nigbana ni yio si ni ohun iṣogo nipa ti ara rẹ̀ nikan, kì yio si ṣe nipa ti ọmọnikeji rẹ̀.
Gal 6:2-4 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ máa ran ara yín lẹ́rù, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú òfin Kristi ṣẹ. Nítorí bí ẹnìkan bá rò pé òun jẹ́ pataki nígbà tí kò jẹ́ nǹkan, ara rẹ̀ ni ó ń tàn jẹ. Kí olukuluku yẹ iṣẹ́ ara rẹ̀ wò, nígbà náà yóo lè ṣògo lórí iṣẹ́ tirẹ̀, kì í ṣe pé kí ó máa fi iṣẹ́ tirẹ̀ wé ti ẹlòmíràn.
Gal 6:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ máa ru ẹrù ọmọnìkejì yín, kí ẹ sì fi bẹ́ẹ̀ mú òfin Kristi ṣẹ. Nítorí bí ènìyàn kan bá ń ro ara rẹ̀ sí ẹnìkan, nígbà tí kò jẹ́ nǹkan, ó ń tan ara rẹ̀ jẹ. Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yẹ iṣẹ́ ara rẹ̀ wò, nígbà náà, ohun ìmú-ṣogo rẹ̀ yóò jẹ́ nínú ti ara rẹ̀ nìkan, kì yóò sì jẹ nínú ti ọmọnìkejì rẹ̀.