Gal 4:4-11
Gal 4:4-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn nigbati akokò kíkun na de, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ jade wá, ẹniti a bí ninu obinrin, ti a bi labẹ ofin, Lati ra awọn ti mbẹ labẹ ofin pada, ki awa ki o le gbà isọdọmọ. Ati nitoriti ẹnyin nṣe ọmọ, Ọlọrun si ti rán Ẹmí Ọmọ rẹ̀ wá sinu ọkàn nyin, ti nke pe, Abba, Baba. Nitorina iwọ kì iṣe ẹrú mọ́, bikoṣe ọmọ; ati bi iwọ ba iṣe ọmọ, njẹ iwọ di arole Ọlọrun nipasẹ Kristi. Ṣugbọn nigbati ẹnyin kò ti mọ̀ Ọlọrun rí, ẹnyin ti nsìnrú fun awọn ti kì iṣe ọlọrun nipa ẹda. Ṣugbọn nisisiyi, nigbati ẹnyin ti mọ̀ Ọlọrun tan, tabi ki a sá kuku wipe, ẹ di mimọ̀ fun Ọlọrun, ẽha ti ri ti ẹ fi tun yipada si alailera ati alagbe ipilẹṣẹ ẹda, labẹ eyiti ẹnyin tun fẹ pada wa sinru? Ẹnyin nkiyesi ọjọ, ati oṣù, ati akokò, ati ọdún. Ẹru nyin mba mi, ki o má ba ṣe pe lasan ni mo ti ṣe lãlã lori nyin.
Gal 4:4-11 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn nígbà tí ó tó àkókò tí ó wọ̀, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá. Obinrin ni ó bí i, ó bí i lábẹ́ òfin àwọn Juu, kí ó lè ra àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin pada, kí á lè sọ wá di ọmọ. Ọlọrun rán ẹ̀mí ọmọ rẹ̀ sinu ọkàn wa, Ẹ̀mí yìí ń ké pé, “Baba!” láti fihàn pé ọmọ ni ẹ jẹ́. Nítorí náà, ẹ kì í ṣe ẹrú mọ́ bíkòṣe ọmọ. Bí ẹ bá wá jẹ́ ọmọ, ẹ di ajogún nípasẹ̀ iṣẹ́ Ọlọrun. Ṣugbọn nígbà tí ẹ kò mọ Ọlọrun, ẹ di ẹrú àwọn ẹ̀dá tí kì í ṣe Ọlọrun. Nisinsinyii ẹ mọ Ọlọrun, tabi kí á kúkú wí pé Ọlọrun mọ̀ yín. Báwo ni ẹ ṣe tún fẹ́ yipada sí àwọn ẹ̀mí tí a kò fi ojú rí, tí wọ́n jẹ́ aláìlera ati aláìní, tí ẹ tún fẹ́ máa lọ ṣe ẹrú wọn? Ẹ̀ ń ya oríṣìíríṣìí ọjọ́ sọ́tọ̀, ẹ̀ ń ranti oṣù titun, àkókò ati àjọ̀dún! Ẹ̀rù yín ń bà mí pé kí gbogbo làálàá mi lórí yín má wá jẹ́ lásán!
Gal 4:4-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kíkún náà dé, Ọlọ́run rán ọmọ rẹ̀ jáde wá, ẹni tí a bí nínú obìnrin tí a bí lábẹ́ òfin. Láti ra àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin padà, kí àwa lè gba ìsọdọmọ, Àti nítorí tí ẹ̀yin jẹ́ ọmọ, Ọlọ́run sì ti rán Ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ wá sínú ọkàn yín, tí ń ké pé, “Ábbà, Baba.” Nítorí náà ìwọ kì í ṣe ẹrú, bí kò ṣe ọmọ; àti bí ìwọ bá ń ṣe ọmọ, ǹjẹ́ ìwọ di àrólé Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí ẹ̀yin kò tí i mọ Ọlọ́run, ẹ̀yin ti ṣe ẹrú fún àwọn tí kì í ṣe Ọlọ́run nípa ìṣẹ̀dá. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nígbà tí ẹ̀yin ti mọ Ọlọ́run tan tàbí kí a sá kúkú wí pé ẹ di mímọ́ fún Ọlọ́run, èéha ti rí tí ẹ tún fi yípadà sí aláìlera àti agbára ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀dá, lábẹ́ èyí tí ẹ̀yin tún fẹ́ padà wá ṣe ẹrú? Ẹ̀yin ń kíyèsi ọjọ́ àti àkókò, àti ọdún. Ẹ̀rù yin ń bà mí, kí o má bà ṣe pé lásán ni mo ṣe làálàá lórí yín.