Gal 4:3-7
Gal 4:3-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gẹgẹ bẹ̃ si li awa, nigbati awa wà li ewe, awa wà li ondè labẹ ipilẹṣẹ ẹda: Ṣugbọn nigbati akokò kíkun na de, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ jade wá, ẹniti a bí ninu obinrin, ti a bi labẹ ofin, Lati ra awọn ti mbẹ labẹ ofin pada, ki awa ki o le gbà isọdọmọ. Ati nitoriti ẹnyin nṣe ọmọ, Ọlọrun si ti rán Ẹmí Ọmọ rẹ̀ wá sinu ọkàn nyin, ti nke pe, Abba, Baba. Nitorina iwọ kì iṣe ẹrú mọ́, bikoṣe ọmọ; ati bi iwọ ba iṣe ọmọ, njẹ iwọ di arole Ọlọrun nipasẹ Kristi.
Gal 4:3-7 Yoruba Bible (YCE)
Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí pẹlu wa. Nígbà tí a jẹ́ ọmọde, a jẹ́ ẹrú àwọn oríṣìíríṣìí ẹ̀mí tí a kò fojú rí. Ṣugbọn nígbà tí ó tó àkókò tí ó wọ̀, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá. Obinrin ni ó bí i, ó bí i lábẹ́ òfin àwọn Juu, kí ó lè ra àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin pada, kí á lè sọ wá di ọmọ. Ọlọrun rán ẹ̀mí ọmọ rẹ̀ sinu ọkàn wa, Ẹ̀mí yìí ń ké pé, “Baba!” láti fihàn pé ọmọ ni ẹ jẹ́. Nítorí náà, ẹ kì í ṣe ẹrú mọ́ bíkòṣe ọmọ. Bí ẹ bá wá jẹ́ ọmọ, ẹ di ajogún nípasẹ̀ iṣẹ́ Ọlọrun.
Gal 4:3-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwa, nígbà tí àwa wà ní èwe, àwa wà nínú ìdè lábẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kíkún náà dé, Ọlọ́run rán ọmọ rẹ̀ jáde wá, ẹni tí a bí nínú obìnrin tí a bí lábẹ́ òfin. Láti ra àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin padà, kí àwa lè gba ìsọdọmọ, Àti nítorí tí ẹ̀yin jẹ́ ọmọ, Ọlọ́run sì ti rán Ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ wá sínú ọkàn yín, tí ń ké pé, “Ábbà, Baba.” Nítorí náà ìwọ kì í ṣe ẹrú, bí kò ṣe ọmọ; àti bí ìwọ bá ń ṣe ọmọ, ǹjẹ́ ìwọ di àrólé Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi.