Gal 4:1-11

Gal 4:1-11 Yoruba Bible (YCE)

Ohun tí mò ń sọ ni pé nígbà tí àrólé bá wà ní ọmọde kò sàn ju ẹrú lọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó ni gbogbo nǹkan tí Baba rẹ̀ fi sílẹ̀. Nítorí pé òun alára wà lábẹ́ àwọn olùtọ́jú, ohun ìní rẹ̀ sì wà ní ìkáwọ́ àwọn alámòójútó títí di àkókò tí baba rẹ̀ ti dá. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí pẹlu wa. Nígbà tí a jẹ́ ọmọde, a jẹ́ ẹrú àwọn oríṣìíríṣìí ẹ̀mí tí a kò fojú rí. Ṣugbọn nígbà tí ó tó àkókò tí ó wọ̀, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá. Obinrin ni ó bí i, ó bí i lábẹ́ òfin àwọn Juu, kí ó lè ra àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin pada, kí á lè sọ wá di ọmọ. Ọlọrun rán ẹ̀mí ọmọ rẹ̀ sinu ọkàn wa, Ẹ̀mí yìí ń ké pé, “Baba!” láti fihàn pé ọmọ ni ẹ jẹ́. Nítorí náà, ẹ kì í ṣe ẹrú mọ́ bíkòṣe ọmọ. Bí ẹ bá wá jẹ́ ọmọ, ẹ di ajogún nípasẹ̀ iṣẹ́ Ọlọrun. Ṣugbọn nígbà tí ẹ kò mọ Ọlọrun, ẹ di ẹrú àwọn ẹ̀dá tí kì í ṣe Ọlọrun. Nisinsinyii ẹ mọ Ọlọrun, tabi kí á kúkú wí pé Ọlọrun mọ̀ yín. Báwo ni ẹ ṣe tún fẹ́ yipada sí àwọn ẹ̀mí tí a kò fi ojú rí, tí wọ́n jẹ́ aláìlera ati aláìní, tí ẹ tún fẹ́ máa lọ ṣe ẹrú wọn? Ẹ̀ ń ya oríṣìíríṣìí ọjọ́ sọ́tọ̀, ẹ̀ ń ranti oṣù titun, àkókò ati àjọ̀dún! Ẹ̀rù yín ń bà mí pé kí gbogbo làálàá mi lórí yín má wá jẹ́ lásán!

Gal 4:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ǹjẹ́ ohun tí mo ń wí ni pé, níwọ̀n ìgbà tí àrólé náà bá wà ní èwe, kò yàtọ̀ nínú ohunkóhun sí ẹrú bí ó tilẹ̀ jẹ́ Olúwa ohun gbogbo. Ṣùgbọ́n ó wà lábẹ́ olùtọ́jú àti ìríjú títí àkókò tí baba ti yàn tẹ́lẹ̀. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwa, nígbà tí àwa wà ní èwe, àwa wà nínú ìdè lábẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kíkún náà dé, Ọlọ́run rán ọmọ rẹ̀ jáde wá, ẹni tí a bí nínú obìnrin tí a bí lábẹ́ òfin. Láti ra àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin padà, kí àwa lè gba ìsọdọmọ, Àti nítorí tí ẹ̀yin jẹ́ ọmọ, Ọlọ́run sì ti rán Ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ wá sínú ọkàn yín, tí ń ké pé, “Ábbà, Baba.” Nítorí náà ìwọ kì í ṣe ẹrú, bí kò ṣe ọmọ; àti bí ìwọ bá ń ṣe ọmọ, ǹjẹ́ ìwọ di àrólé Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí ẹ̀yin kò tí i mọ Ọlọ́run, ẹ̀yin ti ṣe ẹrú fún àwọn tí kì í ṣe Ọlọ́run nípa ìṣẹ̀dá. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nígbà tí ẹ̀yin ti mọ Ọlọ́run tan tàbí kí a sá kúkú wí pé ẹ di mímọ́ fún Ọlọ́run, èéha ti rí tí ẹ tún fi yípadà sí aláìlera àti agbára ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀dá, lábẹ́ èyí tí ẹ̀yin tún fẹ́ padà wá ṣe ẹrú? Ẹ̀yin ń kíyèsi ọjọ́ àti àkókò, àti ọdún. Ẹ̀rù yin ń bà mí, kí o má bà ṣe pé lásán ni mo ṣe làálàá lórí yín.