Gal 3:5-7
Gal 3:5-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina ẹniti o fun nyin li Ẹmí na, ti o si ṣe iṣẹ-agbara larin nyin, nipa iṣẹ ofin li o fi nṣe e bi, tabi nipa igbọran igbagbọ́? Gẹgẹ bi Abrahamu ti gbà Ọlọrun gbọ́, a si kà a si fun u li ododo. Nitorina ki ẹnyin ki o mọ̀ pe awọn ti iṣe ti igbagbọ́, awọn na ni iṣe ọmọ Abrahamu.
Gal 3:5-7 Yoruba Bible (YCE)
Ṣé nítorí pé ẹ̀ ń ṣe iṣẹ́ òfin ni ẹni tí ó fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí fun yín ṣe fun yín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí ó tún ṣiṣẹ́ ìyanu láàrin yín, tabi nítorí pé ẹ gbọ́ ìyìn rere, ẹ sì gbà á? Bí Abrahamu ti gba Ọlọrun gbọ́, tí Ọlọrun wá gbà á gẹ́gẹ́ bí olódodo, kí ó ye yín pé àwọn ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ni ọmọ Abrahamu.
Gal 3:5-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣé Ọlọ́run fún yín ní Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín yín nítorí tí ẹ̀yin pa òfin mọ, tàbí nítorí ẹ ní ìgbàgbọ́ sí ohun tí ẹ gbọ́? Gẹ́gẹ́ bí Abrahamu “Ó gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.” Ẹ jẹ́ kí ó yé é yín nígbà náà pé, àwọn ti ó gbàgbọ́, àwọn náà ní í ṣe ọmọ Abrahamu.