Gal 3:19-25
Gal 3:19-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ ki ha li ofin? a fi kun u nitori irekọja titi irú-ọmọ ti a ti ṣe ileri fun yio fi de; a si ti ipasẹ awọn angẹli ṣe ìlana rẹ̀ lati ọwọ́ alarina kan wá. Njẹ alarina kì iṣe alarina ti ẹnikan, ṣugbọn ọ̀kan li Ọlọrun. Nitorina ofin ha lodi si awọn ileri Ọlọrun bi? Ki a má ri: nitori ibaṣepe a ti fi ofin kan funni, ti o lagbara lati sọni di ãye, nitotọ ododo iba ti ti ipasẹ ofin wá. Ṣugbọn iwe-mimọ́ ti sé gbogbo nkan mọ́ sabẹ ẹ̀ṣẹ, ki a le fi ileri nipa igbagbọ́ ninu Jesu Kristi fun awọn ti o gbagbọ́. Ṣugbọn ki igbagbọ́ to de, a ti pa wa mọ́ labẹ ofin, a si sé wa mọ́ de igbagbọ́ ti a mbọwa fihàn. Nitorina ofin ti jẹ olukọni lati mu ni wá sọdọ Kristi, ki a le da wa lare nipa igbagbọ́. Ṣugbọn lẹhin igbati igbagbọ́ ti de, awa kò si labẹ olukọni mọ́.
Gal 3:19-25 Yoruba Bible (YCE)
Ipò wo wá ni òfin wà? Kí eniyan lè mọ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ ni Ọlọrun ṣe fi òfin kún ìlérí, títí irú-ọmọ tí ó ṣe ìlérí rẹ̀ fún yóo fi dé. Láti ọwọ́ àwọn angẹli ni alárinà ti gba òfin. Ètò tí alárinà bá lọ́wọ́ sí ti kúrò ní ti ẹyọ ẹnìkan. Ṣugbọn ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọrun. Ǹjẹ́ òfin wá lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọrun ni bí? Rárá o! Bí ó bá jẹ́ pé òfin tí a fi fúnni lè sọ eniyan di alààyè, eniyan ìbá lè di olódodo nípa òfin. Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ ti sọ pé ohun gbogbo wà ninu ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ kí á lè fi ìlérí nípa igbagbọ ninu Jesu Kristi fún gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́. Ṣugbọn kí àkókò igbagbọ yìí tó tó, a wà ninu àtìmọ́lé lábẹ́ òfin, a sé wa mọ́ títí di àkókò igbagbọ yìí. Èyí ni pé òfin jẹ́ olùtọ́ wa títí Kristi fi dé, kí á lè dá wa láre nípa igbagbọ. Nígbà tí àkókò igbagbọ ti dé, a kò tún nílò olùtọ́ mọ́.
Gal 3:19-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ kí ha ni òfin? A fi kún un nítorí ìrékọjá títí irú-ọmọ tí a ti ṣe ìlérí fún yóò fi dé; a sì tipasẹ̀ àwọn angẹli ṣe ìlànà rẹ̀ láti ọwọ́ alárinà kan wá. Ǹjẹ́ onílàjà kì í ṣe alárinà ti ẹnìkan, ṣùgbọ́n ọ̀kan ni Ọlọ́run. Nítorí náà òfin ha lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọ́run bí? Kí a má rí i; Nítorí ìbá ṣe pé a ti fi òfin kan fún ni tí ó lágbára láti sọ ni di ààyè nítòótọ́ òdodo ìbá ti tipasẹ̀ òfin wà. Ṣùgbọ́n ìwé mímọ́ ti fi yé wa pé gbogbo ènìyàn ni ń bẹ lábẹ́ ìdè ẹ̀ṣẹ̀, kí a lè fi ìlérí nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi fún àwọn tí ó gbàgbọ́. Ṣùgbọ́n kí ìgbàgbọ́ tó dé, a ti pa wá mọ́ lábẹ́ òfin, a sì sé wa mọ́ de ìgbàgbọ́ tí a ń bọ̀ wá fihàn. Nítorí náà òfin ti jẹ́ olùtọ́jú láti mú ènìyàn wá sọ́dọ̀ Kristi, kí a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí ìgbàgbọ́ ti dé, àwa kò sí lábẹ́ olùtọ́jú mọ́.