Gal 3:10-11
Gal 3:10-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoripe iye awọn ti mbẹ ni ipa iṣẹ ofin mbẹ labẹ ègún: nitoriti a ti kọ ọ pe, Ifibu ni olukuluku ẹniti kò duro ninu ohun gbogbo ti a kọ sinu iwe ofin lati mã ṣe wọn. Nitori o daniloju pe, a kò da ẹnikẹni lare niwaju Ọlọrun nipa iṣẹ ofin: nitoripe, Olododo yio yè nipa igbagbọ́.
Gal 3:10-11 Yoruba Bible (YCE)
A ti fi gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé iṣẹ́ òfin gégùn-ún. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ègbé ni fún gbogbo ẹni tí kò bá máa ṣe ohun gbogbo tí a kọ sinu ìwé òfin.” Ó dájú pé kò sí ẹnikẹ́ni tí Ọlọrun yóo dá láre nípa òfin, nítorí a kà á pé, “Olódodo yóo wà láàyè nípa igbagbọ.”
Gal 3:10-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí pé iye àwọn tí ń bẹ ni ipa iṣẹ́ òfin ń bẹ lábẹ́ ègún: nítorí tí a tí kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí kò dúró nínú ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé òfin láti máa ṣe wọ́n. Nítorí ó dánilójú pé, a kò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú Ọlọ́run nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé, olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́.”