Gal 3:1-5
Gal 3:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
ẸNYIN alaironu ara Galatia, tani ha tàn nyin jẹ, ki ẹnyin ki o máṣe gbà otitọ gbọ́, li oju ẹniti a fi Jesu Kristi hàn gbangba lãrin nyin li ẹniti a kàn mọ agbelebu. Kìki eyi ni mo fẹ mọ̀ lọwọ nyin pe, Nipa iṣẹ ofin li ẹnyin gbà Ẹmí bi, tabi nipa igbọran igbagbọ́? Bayi li ẹnyin ṣe alaironu to? ẹnyin ti o ti bẹ̀rẹ nipa ti Ẹmí a ha ṣe nyin pé nisisiyi nipa ti ara? Ẹnyin ha ti jìya ọ̀pọlọpọ nkan wọnni lasan? bi o tilẹ ṣepe lasan ni. Nitorina ẹniti o fun nyin li Ẹmí na, ti o si ṣe iṣẹ-agbara larin nyin, nipa iṣẹ ofin li o fi nṣe e bi, tabi nipa igbọran igbagbọ́?
Gal 3:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ará Galatia, ẹ mà kúkú gọ̀ o! Ta ni ń dì yín rí? Ẹ̀yin tí a gbé Jesu Kristi tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu sí níwájú gbangba! Nǹkankan péré ni mo fẹ́ bi yín: ṣé nípa iṣẹ́ òfin ni ẹ fi gba Ẹ̀mí ni tabi nípa ìgbọràn igbagbọ? Àṣé ẹ ṣiwèrè tóbẹ́ẹ̀! Ẹ bẹ̀rẹ̀ pẹlu nǹkan ti ẹ̀mí, ẹ wá fẹ́ fi nǹkan ti ara parí! Gbogbo ìyà tí ẹ ti jẹ á wá jẹ́ lásán? Kò lè jẹ́ lásán! Ṣé nítorí pé ẹ̀ ń ṣe iṣẹ́ òfin ni ẹni tí ó fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí fun yín ṣe fun yín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí ó tún ṣiṣẹ́ ìyanu láàrin yín, tabi nítorí pé ẹ gbọ́ ìyìn rere, ẹ sì gbà á?
Gal 3:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀yin aláìnírònú ará Galatia! Ta ní ha tàn yín jẹ, kí ẹ̀yin má ṣe gba òtítọ́ gbọ́? Ní ojú ẹni tí a fi Jesu Kristi hàn gbangba láàrín yín ni ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú. Kìkì èyí ni mo fẹ́ béèrè lọ́wọ́ yín: Nípa iṣẹ́ òfin ni ẹ̀yin gba Ẹ̀mí bí, tàbí nípa ìgbọ́ràn pẹ̀lú ìgbàgbọ́? Báyìí ni ẹ̀yin ṣe jẹ òmùgọ̀ tó bí? Ẹ̀yin tí ó ti bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ìgbàgbọ́ yín nípa ti Ẹ̀mí, ṣé a ti wá sọ yín di pípé nípa ti ara ni? Ẹ̀yin ha ti jìyà ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan wọ̀nyí lásán? Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ lásán ni. Ṣé Ọlọ́run fún yín ní Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín yín nítorí tí ẹ̀yin pa òfin mọ, tàbí nítorí ẹ ní ìgbàgbọ́ sí ohun tí ẹ gbọ́?