Gal 2:9-10
Gal 2:9-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati nigbati Jakọbu, ati Kefa, ati Johanu, awọn ẹniti o dabi ọwọ̀n, woye ore-ọfẹ ti a fifun mi, nwọn si fi ọwọ́ ọtún ìdapọ fun emi ati Barnaba, pe ki awa ki o mã lọ sọdọ awọn Keferi, ati awọn sọdọ awọn onila. Kìki nwọn fẹ ki a mã ranti awọn talakà, ohun kanna gan ti mo nfi titaratitara ṣe pẹlu.
Gal 2:9-10 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jakọbu, Peteru ati Johanu, tí àwọn eniyan ń wò bí òpó ninu ìjọ, rí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun ti fi fún mi, wọ́n bọ èmi ati Banaba lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí àmì ìdàpọ̀, wọ́n ní kí àwa lọ sáàrin àwọn tí kì í ṣe Juu bí àwọn náà ti ń lọ sáàrin àwọn tí ó kọlà. Nǹkankan ni wọ́n sọ fún wa, pé kí á ranti àwọn talaka láàrin àwọn tí ó kọlà. Òun gan-an ni mo sì ti dàníyàn láti máa ṣe.
Gal 2:9-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jakọbu, Peteru, àti Johanu, àwọn ẹni tí ó dàbí ọ̀wọ́n, fún èmi àti Barnaba ni ọwọ́ ọ̀tún ìdàpọ̀ nígbà tí wọ́n rí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, wọ́n sì gbà pé kí àwa náà tọ àwọn aláìkọlà lọ, nígbà ti àwọn náà lọ sọ́dọ̀ àwọn Júù. Ohun gbogbo tí wọ́n béèrè fún ni wí pé, kí a máa rántí àwọn tálákà, ohun kan náà gan an tí mo ń làkàkà láti ṣe.