Gal 2:11-14
Gal 2:11-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn nigbati Peteru wá si Antioku, mo ta kò o li oju ara rẹ̀, nitoriti o jẹ ẹniti a ba bawi. Nitoripe ki awọn kan ti o ti ọdọ Jakọbu wá to de, o ti mba awọn Keferi jẹun: ṣugbọn nigbati nwọn de, o fà sẹhin, o si yà ara rẹ̀ si apakan, o mbẹ̀ru awọn ti iṣe onila. Awọn Ju ti o kù si jùmọ ṣe agabagebe bẹ̃ gẹgẹ pẹlu rẹ̀; tobẹ̃ ti nwọn si fi agabagebe wọn fà Barnaba tikararẹ lọ. Ṣugbọn nigbati mo ri pe nwọn kò rìn dẽdẽ gẹgẹ bi otitọ ihinrere, mo wi fun Peteru niwaju gbogbo wọn pe, Bi iwọ, ti iṣe Ju, ba nrìn gẹgẹ bi ìwa awọn Keferi, laiṣe bi awọn Ju, ẽṣe ti iwọ fi nfi agbara mu awọn Keferi lati mã rìn bi awọn Ju?
Gal 2:11-14 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn nígbà tí Peteru wà ní Antioku, mo takò ó lojukooju nítorí ó ṣe ohun ìbáwí. Nítorí kí àwọn kan tó ti ọ̀dọ̀ Jakọbu dé, Peteru ti ń bá àwọn onigbagbọ tí kì í ṣe Juu jẹun. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí fà sẹ́yìn, ó ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, nítorí ó ń bẹ̀rù àwọn tí wọ́n fẹ́ kí gbogbo onigbagbọ kọlà. Àwọn Juu yòókù bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àgàbàgebè pẹlu Peteru. Wọ́n tilẹ̀ mú Banaba pàápàá wọ ẹgbẹ́ àgàbàgebè wọn! Nígbà tí mo rí i pé ohun tí wọn ń ṣe kò bá òtítọ́ ìyìn rere mu, mo wí fún Peteru níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ tí ó jẹ́ Juu bá ti ń ṣe bí àwọn yòókù, tí o kò ṣe bí àṣà àwọn Juu, kí ló dé tí o fi fẹ́ kí àwọn tí kì í ṣe Juu ṣe ara wọn bíi Juu?”
Gal 2:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n nígbà tí Peteru wá sí Antioku, mo takò ó lójú ara rẹ̀, nítorí tí ó jẹ̀bi, mo sì bá a wí. Nítorí pé kí àwọn kan tí ó ti ọ̀dọ̀ Jakọbu wá tó dé, ó ti ń ba àwọn aláìkọlà jẹun; Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé, ó fàsẹ́yìn, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà nítorí ó bẹ̀rù àwọn ti ó kọlà. Àwọn Júù tí ó kù pawọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti jùmọ̀ ṣe àgàbàgebè, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn sì fi àgàbàgebè wọn si Barnaba lọ́nà. Nígbà tí mo rí i pé wọn kò rìn déédé gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ìhìnrere, mo wí fún Peteru níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ, tí ì ṣe Júù ba ń rìn gẹ́gẹ́ bí ìwà àwọn kèfèrí, èéṣe tí ìwọ fi ń fi agbára mu àwọn keferi láti máa rìn bí àwọn Júù?