Gal 1:6-9
Gal 1:6-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnu yà mi nitoriti ẹ tete kuro lọdọ ẹniti o pè nyin sinu ore-ọfẹ Kristi, si ihinrere miran: Eyiti kì iṣe omiran; bi o tilẹ ṣe pe awọn kan wà ti nyọ nyin lẹnu, ti nwọn si nfẹ yi ihinrere Kristi pada. Ṣugbọn bi o ṣe awa ni, tabi angẹli kan lati ọrun wá, li o ba wasu ihinrere miran fun nyin ju eyiti a ti wasu fun nyin lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu. Bi awa ti wi ṣaju, bẹ̃ni mo si tún wi nisisiyi pe, Bi ẹnikan ba wasu ihinrere miran fun nyin jù eyiti ẹnyin ti gbà lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu.
Gal 1:6-9 Yoruba Bible (YCE)
Ẹnu yà mí pé ẹ ti kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín nípa oore-ọ̀fẹ́ Kristi, ẹ ti yára yipada sí ìyìn rere mìíràn. Kò sí ìyìn rere mìíràn ju pé àwọn kan wà tí wọn ń yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n fẹ́ yí ìyìn rere Kristi pada. Ṣugbọn bí àwa fúnra wa tabi angẹli láti ọ̀run bá waasu ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí a ti waasu fun yín, kí olúwarẹ̀ di ẹni ègbé. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, mo tún ń wí nisinsinyii pé bí ẹnikẹ́ni bá waasu ìyìn rere mìíràn fun yín, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ gbà, kí olúwarẹ̀ di ẹni ègbé.
Gal 1:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó yà mi lẹ́nu pé ẹ tètè yapa kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín sínú oore-ọ̀fẹ́ Kristi, sí ìhìnrere mìíràn: Nítòótọ́, kò sí ìhìnrere mìíràn: bí ó tilẹ̀ ṣe pé àwọn kan wà, tí ń yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n sì ń fẹ́ yí ìhìnrere Kristi padà. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe àwa ni tàbí angẹli kan láti ọ̀run wá, ni ó bá wàásù ìhìnrere mìíràn fún yín ju èyí tí a tí wàásù rẹ̀ fún yín lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé! Bí àwa ti wí ṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni mo sì tún wí nísinsin yìí pé: Bí ẹnìkan bá wàásù ìhìnrere mìíràn fún yín ju èyí tí ẹ̀yin tí gbà lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé!