Gal 1:21-24
Gal 1:21-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lẹhin na mo si wá si ẹkùn Siria ati ti Kilikia; Mo sì jẹ ẹniti a kò mọ̀ li oju fun awọn ijọ ti o wà ninu Kristi ni Judea: Ṣugbọn kìki nwọn ti gbọ́ pe, Ẹniti o ti nṣe inunibini si wa rí, si nwasu igbagbọ́ na nisisiyi, ti o ti mbajẹ nigbakan rí. Nwọn si nyin Ọlọrun logo nitori mi.
Gal 1:21-24 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà mo lọ sí agbègbè Siria ati ti Silisia. Àwọn ìjọ Kristi tí ó wà ní Judia kò mọ̀ mí sójú. Ṣugbọn wọ́n ń gbọ́ pé, “Ẹni tí ó ti ń fìtínà wa tẹ́lẹ̀ rí ti ń waasu ìyìn rere igbagbọ tí ó fẹ́ parun nígbà kan rí.” Wọ́n bá ń yin Ọlọrun lógo nítorí mi.
Gal 1:21-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn náà mo sì wá sí agbègbè Siria àti ti Kilikia; Mo sì jẹ́ ẹni tí a kò mọ̀ lójú fún àwọn ìjọ tí ó wà nínú Kristi ni Judea: Wọ́n kàn gbọ́ ìròyìn wí pé, “Ẹni tí ó tí ń ṣe inúnibíni sí wa rí, ní ìsinsin yìí ti ń wàásù ìgbàgbọ́ náà tí ó ti gbìyànjú láti bàjẹ́ nígbà kan rí.” Wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo nítorí mi.