Gal 1:1-5
Gal 1:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
PAULU, Aposteli (ki iṣe lati ọdọ enia wá, tabi nipa enia, ṣugbọn nipa Jesu Kristi, ati Ọlọrun Baba, ẹniti o jí i dide kuro ninu okú), Ati gbogbo awọn arakunrin ti o wà pẹlu mi, si awọn ijọ Galatia: Ore-ọfẹ si nyin ati alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Jesu Kristi Oluwa wa, Ẹniti o fi on tikalarẹ̀ fun ẹ̀ṣẹ wa, ki o le gbà wa kuro ninu aiye buburu isisiyi, gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun ati Baba wa: Ẹniti ogo wà fun lai ati lailai. Amin.
Gal 1:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Èmi Paulu, kì í ṣe eniyan ni ó pè mí láti jẹ́ aposteli, n kò sì ti ọ̀dọ̀ eniyan gba ìpè, Jesu Kristi ati Ọlọrun Baba, tí ó jí Jesu dìde, ni ó pè mí. Èmi ati gbogbo arakunrin tí ó wà lọ́dọ̀ mi ni à ń kọ ìwé yìí sí àwọn ìjọ Galatia. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia Ọlọrun, Baba wa, wà pẹlu yín ati ti Oluwa Jesu Kristi, ẹni tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò lọ́wọ́ ayé wa burúkú yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọrun Baba wa, ẹni tí ògo yẹ fún lae ati laelae. Amin.
Gal 1:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Paulu, aposteli tí a rán kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn wá, tàbí nípa ènìyàn, ṣùgbọ́n nípa Jesu Kristi àti Ọlọ́run Baba, ẹni tí ó jí i dìde kúrò nínú òkú. Àti gbogbo àwọn arákùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi, Sí àwọn ìjọ ní Galatia: Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jesu Kristi Olúwa, ẹni tí ó fi òun tìkára rẹ̀ dípò ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò nínú ayé búburú ìsinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa, ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.