Gal 1:1-14
Gal 1:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
PAULU, Aposteli (ki iṣe lati ọdọ enia wá, tabi nipa enia, ṣugbọn nipa Jesu Kristi, ati Ọlọrun Baba, ẹniti o jí i dide kuro ninu okú), Ati gbogbo awọn arakunrin ti o wà pẹlu mi, si awọn ijọ Galatia: Ore-ọfẹ si nyin ati alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Jesu Kristi Oluwa wa, Ẹniti o fi on tikalarẹ̀ fun ẹ̀ṣẹ wa, ki o le gbà wa kuro ninu aiye buburu isisiyi, gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun ati Baba wa: Ẹniti ogo wà fun lai ati lailai. Amin. Ẹnu yà mi nitoriti ẹ tete kuro lọdọ ẹniti o pè nyin sinu ore-ọfẹ Kristi, si ihinrere miran: Eyiti kì iṣe omiran; bi o tilẹ ṣe pe awọn kan wà ti nyọ nyin lẹnu, ti nwọn si nfẹ yi ihinrere Kristi pada. Ṣugbọn bi o ṣe awa ni, tabi angẹli kan lati ọrun wá, li o ba wasu ihinrere miran fun nyin ju eyiti a ti wasu fun nyin lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu. Bi awa ti wi ṣaju, bẹ̃ni mo si tún wi nisisiyi pe, Bi ẹnikan ba wasu ihinrere miran fun nyin jù eyiti ẹnyin ti gbà lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu. Njẹ nisisiyi enia ni emi nyi lọkàn pada tabi Ọlọrun? tabi enia ni emi nfẹ lati wù? nitoripe bi emi ba si nwù enia, emi kì yio le ṣe iranṣẹ Kristi. Ṣugbọn, ará, mo fẹ ki ẹ mọ̀ pe ihinrere ti mo ti wasu kì iṣe nipa ti enia. Nitori kì iṣe lọwọ enia ni mo ti gbà a, bẹ̃li a kò fi kọ́ mi, ṣugbọn nipa ifihan Jesu Kristi. Nitori ẹnyin ti gburó ìwa-aiye mi nigba atijọ ninu ìsin awọn Ju, bi mo ti ṣe inunibini si ijọ enia Ọlọrun rekọja ãlà, ti mo si bà a jẹ: Mo si ta ọpọlọpọ awọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ ninu isin awọn Ju larin awọn ara ilu mi, mo si ni itara lọpọlọpọ si ofin atọwọdọwọ awọn baba mi.
Gal 1:1-14 Yoruba Bible (YCE)
Èmi Paulu, kì í ṣe eniyan ni ó pè mí láti jẹ́ aposteli, n kò sì ti ọ̀dọ̀ eniyan gba ìpè, Jesu Kristi ati Ọlọrun Baba, tí ó jí Jesu dìde, ni ó pè mí. Èmi ati gbogbo arakunrin tí ó wà lọ́dọ̀ mi ni à ń kọ ìwé yìí sí àwọn ìjọ Galatia. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia Ọlọrun, Baba wa, wà pẹlu yín ati ti Oluwa Jesu Kristi, ẹni tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò lọ́wọ́ ayé wa burúkú yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọrun Baba wa, ẹni tí ògo yẹ fún lae ati laelae. Amin. Ẹnu yà mí pé ẹ ti kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín nípa oore-ọ̀fẹ́ Kristi, ẹ ti yára yipada sí ìyìn rere mìíràn. Kò sí ìyìn rere mìíràn ju pé àwọn kan wà tí wọn ń yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n fẹ́ yí ìyìn rere Kristi pada. Ṣugbọn bí àwa fúnra wa tabi angẹli láti ọ̀run bá waasu ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí a ti waasu fun yín, kí olúwarẹ̀ di ẹni ègbé. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, mo tún ń wí nisinsinyii pé bí ẹnikẹ́ni bá waasu ìyìn rere mìíràn fun yín, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ gbà, kí olúwarẹ̀ di ẹni ègbé. Ṣé ojurere eniyan ni mò ń wá nisinsinyii, tabi ti Ọlọrun? Àbí ohun tí ó wu eniyan ni mo fẹ́ máa ṣe? Bí ó bá jẹ́ pé ohun tí ó wu eniyan ni mò ń ṣe sibẹ, èmi kì í ṣe iranṣẹ Kristi. Ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìyìn rere tí mò ń waasu kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ eniyan. Kì í ṣe ọwọ́ eniyan ni mo ti gbà á, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe eniyan ni ó kọ́ mi. Jesu Kristi ni ó fihàn mí. Nítorí ẹ ti gbúròó ìwà mi látijọ́ nígbà tí mo wà ninu ẹ̀sìn ti Juu, pé mò ń fìtínà ìjọ Ọlọrun ju bí ó ti yẹ lọ. Mo sa gbogbo ipá mi láti pa á run. Ninu ẹ̀sìn Juu, mo ta ọpọlọpọ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi ninu orílẹ̀-èdè mi yọ. Mo ní ìtara rékọjá ààlà ninu àṣà ìbílẹ̀ àwọn baba-ńlá mi.
Gal 1:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Paulu, aposteli tí a rán kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn wá, tàbí nípa ènìyàn, ṣùgbọ́n nípa Jesu Kristi àti Ọlọ́run Baba, ẹni tí ó jí i dìde kúrò nínú òkú. Àti gbogbo àwọn arákùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi, Sí àwọn ìjọ ní Galatia: Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jesu Kristi Olúwa, ẹni tí ó fi òun tìkára rẹ̀ dípò ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò nínú ayé búburú ìsinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa, ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín. Ó yà mi lẹ́nu pé ẹ tètè yapa kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín sínú oore-ọ̀fẹ́ Kristi, sí ìhìnrere mìíràn: Nítòótọ́, kò sí ìhìnrere mìíràn: bí ó tilẹ̀ ṣe pé àwọn kan wà, tí ń yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n sì ń fẹ́ yí ìhìnrere Kristi padà. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe àwa ni tàbí angẹli kan láti ọ̀run wá, ni ó bá wàásù ìhìnrere mìíràn fún yín ju èyí tí a tí wàásù rẹ̀ fún yín lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé! Bí àwa ti wí ṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni mo sì tún wí nísinsin yìí pé: Bí ẹnìkan bá wàásù ìhìnrere mìíràn fún yín ju èyí tí ẹ̀yin tí gbà lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé! Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ènìyàn ni èmi ń wá ojúrere rẹ̀ ní tàbí Ọlọ́run? Tàbí ènìyàn ni èmi ń fẹ́ láti wù bí? Bí èmi bá ń fẹ́ láti wu ènìyàn, èmi kò lè jẹ́ ìránṣẹ́ Kristi. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀, ará, pé ìhìnrere tí mo tí wàásù kì í ṣe láti ipa ènìyàn. N kò gbà á lọ́wọ́ ènìyàn kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi kọ́ mi, ṣùgbọ́n mo gbà á nípa ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi. Nítorí ẹ̀yin ti gbúròó ìgbé ayé mi nígbà àtijọ́ nínú ìsìn àwọn Júù, bí mo tí ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rékọjá ààlà, tí mo sì lépa láti bà á jẹ́: Mo sì ta ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ nínú ìsìn àwọn Júù láàrín àwọn ìran mi, mo sì ni ìtara lọ́pọ̀lọpọ̀ sì òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn baba mi.