Esr 9:8-9
Esr 9:8-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ nisisiyi fun igba diẹ, li a si fi ore-ọfẹ fun wa lati ọdọ Oluwa Ọlọrun wa wá lati salà, ati lati fi ẽkàn fun wa ni ibi mimọ́ rẹ̀, ki Ọlọrun wa ki o le mu oju wa mọlẹ, ki o si tun wa gbe dide diẹ ninu oko-ẹrú wa. Nitoripe ẹrú li awa iṣe; ṣugbọn Ọlọrun wa kò kọ̀ wa silẹ li oko ẹrú wa, ṣugbọn o ti nawọ́ ãnu rẹ̀ si wa li oju awọn ọba Persia, lati tun mu wa yè, lati gbe ile Ọlọrun wa duro, ati lati tun ahoro rẹ̀ ṣe, ati lati fi odi kan fun wa ni Juda, ati ni Jerusalemu.
Esr 9:8-9 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn fún ìgbà díẹ̀ ní àkókò yìí, OLUWA Ọlọrun wa, o ṣàánú wa, o dá díẹ̀ sí ninu wa, à ń gbé ní àìléwu ní ibi mímọ́ rẹ. O jẹ́ kí ara dẹ̀ wá díẹ̀ ní oko ẹrú, o sì ń mú inú wa dùn. Ẹrú ni wá; sibẹ ìwọ Ọlọrun wa kò fi wá sílẹ̀ ninu oko ẹrú, ṣugbọn o fi ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa, lọ́dọ̀ àwọn ọba Pasia; o sọ wá jí láti kọ́ ilé Ọlọrun wa, láti tún àwọn àlàpà rẹ̀ mọ ati láti mọ odi yí Judia ati Jerusalẹmu ká.
Esr 9:8-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí, fún ìgbà díẹ̀, ni a ti fi oore-ọ̀fẹ́ fún wa láti ọ̀dọ̀ OLúWA Ọlọ́run wa wá láti sálà, àti láti fi èèkàn fún wa ni ibi mímọ́ rẹ̀, nítorí kí Ọlọ́run kí ó lè mú ojú wa mọ́lẹ̀, kí ó sì tún wa gbé dìde díẹ̀ kúrò nínú ìgbèkùn wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa jẹ́ ẹrú, Ọlọ́run wa kò fi wa sílẹ̀ nínú ìgbèkùn wa. Ó ti fi àánú hàn fún wa ni iwájú àwọn ọba Persia: Ó ti fún wa ní ìgbé ayé tuntun láti tún odi ilé Ọlọ́run wa mọ, kí a sì tún àwókù rẹ̀ ṣe, ó sì fi odi ààbò fún wa ní Juda àti ní Jerusalẹmu.