Esr 9:6-7
Esr 9:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mo si wipe, Ọlọrun mi, oju tì mi, iṣãju si ṣe mi lati gbe oju mi soke si ọdọ rẹ, Ọlọrun mi, nitoriti ẹ̀ṣẹ wa di pupọ li ori wa, ẹbi wa si tobi titi de awọn ọrun. Lati ọjọ awọn baba wa li awa ti wà ninu ẹbi nla titi di oni; ati nitori ẹ̀ṣẹ wa li a fi awa, awọn ọba wa, ati awọn alufa wa, le awọn ọba ilẹ wọnni lọwọ fun idà, fun igbèkun, ati fun ikogun, ati fun idamu oju, gẹgẹ bi o ti ri li oni oloni.
Esr 9:6-7 Yoruba Bible (YCE)
“Ọlọrun mi, ojú tì mí tóbẹ́ẹ̀ tí n kò lè gbójú sókè níwájú rẹ. Ìwà burúkú wa pọ̀ pupọ níwájú rẹ, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ní ìpele ìpele, sì ga títí kan ọ̀run. Láti ayé àwọn baba wa títí di ìsinsìnyìí, ni àwa eniyan rẹ ti ń dẹ́ṣẹ̀ lọpọlọpọ. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, àwọn ọba ati àwọn alufaa wa ti bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọba ilẹ̀ àjèjì; wọ́n pa wá, wọ́n dè wá ní ìgbèkùn, wọ́n sì kó wa lẹ́rù. A wá di ẹni ẹ̀gàn títí di òní.
Esr 9:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo sì gbàdúrà: “Ojú tì mí gidigidi, tí n kò fi lè gbé ojú mi sókè sí ọ̀dọ̀ rẹ, Ọlọ́run mi, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wá di púpọ̀ ní orí wa, ẹ̀bi wa sì ga kan àwọn ọ̀run. Láti ọjọ́ àwọn baba wá ni ẹ̀bi wa ti pọ̀ jọjọ títí di ìsinsin yìí. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, àwa àti àwọn ọba wa àti àwọn àlùfáà wa ni a ti sọ di ẹni idà, ẹni ìgbèkùn, ìkógun àti ẹni ẹ̀sín lọ́wọ́ àwọn àjèjì ọba, bí ó ti rí lónìí.