Esr 9:13-15
Esr 9:13-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati lẹhin gbogbo eyi ti o de si wa nitori iṣe buburu wa, ati nitori ẹbi wa nla, nitoripe iwọ Ọlọrun wa ti dá wa si ju bi o ti yẹ lọ fun aiṣedede wa, o si fi iru igbala bi eyi fun wa; Awa iba ha tun ru ofin rẹ? ki awa ki o si ma ba awọn enia irira wọnyi dá ana? iwọ kì o ha binu si wa titi iwọ o fi pa wa run tan, tobẹ̃ ti ẹnikan kò si ni kù, tabi ẹnikan ti o sala? Olododo ni iwọ Oluwa Ọlọrun Israeli: awa ni iyokù ati asala gẹgẹ bi o ti ri li oni yi: wò o, awa duro niwaju rẹ ninu ẹbi wa, nitoripe awa ki o le duro niwaju rẹ nitori eyi.
Esr 9:13-15 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa, nítorí ìwà burúkú wa ati ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí a dá, a rí i pé ìyà tí ìwọ Ọlọrun fi jẹ wá kéré sí ẹ̀ṣẹ̀ wa; o jẹ́ kí àwa tí a pọ̀ tó báyìí ṣẹ́kù sílẹ̀. Ǹjẹ́ àwa tí a ṣẹ́kù yìí tún gbọdọ̀ máa rú òfin rẹ, kí á máa fẹ́ aya láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń ṣe ohun ìríra? Ǹjẹ́ o kò ní bínú sí wa tóbẹ́ẹ̀ tí o óo fi pa wá run, tí a kò fi ní ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan mọ́ tabi kí ẹyọ ẹnìkan sá àsálà? OLUWA Ọlọrun Israẹli, olódodo ni ọ́, nítorí díẹ̀ ninu wa ṣẹ́kù tí a sá àsálà títí di òní yìí. A wà níwájú rẹ báyìí pẹlu ẹ̀ṣẹ̀ wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó lè dúró níwájú rẹ báyìí.”
Esr 9:13-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wa jẹ́ àyọríṣí iṣẹ́ búburú wa àti ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ńlá wa, síbẹ̀, Ọlọ́run wa, ìjìyà ti ìwọ fún wa kéré si ìjìyà tí ó yẹ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti a dá, ìwọ sì fún wa ní àwọn ènìyàn tó ṣẹ́kù bí èyí. Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwa tún yẹ̀ kúrò nínú àṣẹ rẹ, kí a sì máa ṣe ìgbéyàwó papọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọn ti ṣe onírúurú ohun ìríra báyìí? Ṣe ìwọ kò ní bínú sí wa láti pa wá run tí kì yóò sẹ́ ku ẹnikẹ́ni tí yóò là? Ìwọ OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, ìwọ jẹ́ olódodo! Àwa ìgbèkùn tí ó ṣẹ́kù bí ó ti rí lónìí. Àwa dúró níwájú rẹ nínú ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nítorí èyí ẹnikẹ́ni nínú wa kò lè dúró níwájú rẹ”.