Esr 6:19-22
Esr 6:19-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn ọmọ igbekun si ṣe ajọ irekọja li ọjọ kẹrinla oṣu ekini. Nitoriti awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi ti wẹ̀ ara wọn mọ́ bi ẹnikan, gbogbo wọn li o si mọ́, nwọn si pa ẹran irekọja fun gbogbo awọn ọmọ igbekun, ati fun awọn arakunrin wọn, awọn alufa, ati fun awọn tikara wọn. Awọn ọmọ Israeli ti o ti inu igbekun pada bọ̀, ati gbogbo iru awọn ti o ti ya ara wọn si ọdọ wọn kuro ninu ẽri awọn keferi ilẹ na, lati ma ṣe afẹri Oluwa Ọlọrun Israeli, si jẹ àse irekọja. Nwọn si fi ayọ̀ ṣe ajọ aiwukara li ọjọ meje: nitoriti Oluwa ti mu wọn yọ̀, nitoriti o yi ọkàn ọba Assiria pada si ọdọ wọn, lati mu ọwọ wọn le ninu iṣẹ ile Ọlọrun, Ọlọrun Israeli.
Esr 6:19-22 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kẹrinla, oṣù kinni ọdún tí ó tẹ̀lé e, àwọn Juu tí wọ́n pada láti oko ẹrú ṣe ayẹyẹ Àjọ Ìrékọjá. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ya ara wọn sí mímọ́ lápapọ̀, fún ayẹyẹ náà. Wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Àjọ Ìrékọjá fún àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú, wọ́n pa fún àwọn alufaa ẹlẹgbẹ́ wọn, ati fún àwọn tìkara wọn. Gbogbo àwọn Juu tí wọ́n pada láti oko ẹrú ati àwọn tí wọ́n kọ ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà sílẹ̀ láti sin OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí wọn ń bá wọn gbé ní ilẹ̀ náà, tí wọ́n sì wá síbi ayẹyẹ náà pẹlu wọn, ni wọ́n jọ jẹ àsè náà. Ọjọ́ meje ni wọ́n fi fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ayẹyẹ Àjọ Àìwúkàrà, nítorí pé Ọlọrun ti fún wọn ní ayọ̀ nítorí inú ọba Asiria tí ó yọ́ sí wọn, tí ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tún ilé Ọlọrun Israẹli kọ́.
Esr 6:19-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kẹrìnlá ti oṣù Nísàn (oṣù kẹrin), àwọn tí a kó ní ìgbèkùn ṣe ayẹyẹ àjọ ìrékọjá. Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì jẹ́ mímọ́. Àwọn ará Lefi pa ọ̀dọ́-àgùntàn ti àjọ ìrékọjá fún gbogbo àwọn tí a kó ní ìgbèkùn, fún àwọn àlùfáà arákùnrin wọn àti fún ara wọn. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli tí ó ti dé láti ìgbèkùn jẹ ẹ́ lápapọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ti ya ara wọn kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ àìmọ́ ti àwọn kèfèrí aládùúgbò wọn láti wá OLúWA Ọlọ́run Israẹli. Fún ọjọ́ méje, wọ́n ṣe ayẹyẹ àkàrà àìwú pẹ̀lú àjẹtì àkàrà. Nítorí tí OLúWA ti kún wọn pẹ̀lú ayọ̀ nípa yíyí ọkàn ọba Asiria padà, tí ó fi ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ ilé Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli.