Esr 6:16-22

Esr 6:16-22 Yoruba Bible (YCE)

Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli: àwọn alufaa, àwọn ẹ̀yà Lefi ati àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé bá fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ayẹyẹ ìyàsímímọ́ tẹmpili náà. Ọgọrun-un ọ̀dọ́ akọ mààlúù, igba (200) àgbò, ati irinwo (400) ọ̀dọ́ aguntan ni wọ́n fi rú ẹbọ ìyàsímímọ́ náà. Wọ́n sì fi ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀yà Israẹli mejeejila. Wọ́n sì fi àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi sí ipò wọn ninu iṣẹ́ ìsìn inú Tẹmpili, ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ ninu ìwé Mose. Ní ọjọ́ kẹrinla, oṣù kinni ọdún tí ó tẹ̀lé e, àwọn Juu tí wọ́n pada láti oko ẹrú ṣe ayẹyẹ Àjọ Ìrékọjá. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ya ara wọn sí mímọ́ lápapọ̀, fún ayẹyẹ náà. Wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Àjọ Ìrékọjá fún àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú, wọ́n pa fún àwọn alufaa ẹlẹgbẹ́ wọn, ati fún àwọn tìkara wọn. Gbogbo àwọn Juu tí wọ́n pada láti oko ẹrú ati àwọn tí wọ́n kọ ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà sílẹ̀ láti sin OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí wọn ń bá wọn gbé ní ilẹ̀ náà, tí wọ́n sì wá síbi ayẹyẹ náà pẹlu wọn, ni wọ́n jọ jẹ àsè náà. Ọjọ́ meje ni wọ́n fi fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ayẹyẹ Àjọ Àìwúkàrà, nítorí pé Ọlọrun ti fún wọn ní ayọ̀ nítorí inú ọba Asiria tí ó yọ́ sí wọn, tí ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tún ilé Ọlọrun Israẹli kọ́.

Esr 6:16-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Israẹli—àwọn àlùfáà, àwọn Lefi àti àwọn ìgbèkùn tí ó padà, ṣe ayẹyẹ yíya ilé Ọlọ́run sí mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀. Fún yíya ilé Ọlọ́run yìí sí mímọ́, wọ́n pa ọgọ́rùn-ún akọ màlúù (100), ọgọ́rùn-ún méjì àgbò (200) àti ọgọ́ọ̀rún mẹ́rin akọ ọ̀dọ́-àgùntàn (400), àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Israẹli, àgbò méjìlá (12), ọ̀kọ̀ọ̀kan fún olúkúlùkù àwọn ẹ̀yà Israẹli. Wọ́n sì fi àwọn àlùfáà sí àwọn ìpín wọ́n àti àwọn Lefi sì ẹgbẹẹgbẹ́ wọn fún ìsin ti Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú ìwé Mose. Ní ọjọ́ kẹrìnlá ti oṣù Nísàn (oṣù kẹrin), àwọn tí a kó ní ìgbèkùn ṣe ayẹyẹ àjọ ìrékọjá. Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì jẹ́ mímọ́. Àwọn ará Lefi pa ọ̀dọ́-àgùntàn ti àjọ ìrékọjá fún gbogbo àwọn tí a kó ní ìgbèkùn, fún àwọn àlùfáà arákùnrin wọn àti fún ara wọn. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli tí ó ti dé láti ìgbèkùn jẹ ẹ́ lápapọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ti ya ara wọn kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ àìmọ́ ti àwọn kèfèrí aládùúgbò wọn láti wá OLúWA Ọlọ́run Israẹli. Fún ọjọ́ méje, wọ́n ṣe ayẹyẹ àkàrà àìwú pẹ̀lú àjẹtì àkàrà. Nítorí tí OLúWA ti kún wọn pẹ̀lú ayọ̀ nípa yíyí ọkàn ọba Asiria padà, tí ó fi ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ ilé Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli.