Esr 5:6-17

Esr 5:6-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

Atunkọ iwe da ti Tatnai, bãlẹ ni ihahin-odò, ati Ṣetar-bosnai, ati awọn ẹgbẹ rẹ̀ rán si Dariusi ọba: awọn ara Afarsaki ti ihahin-odò. Nwọn fi iwe ranṣẹ si i, ninu eyiti a kọ bayi; Si Dariusi, ọba, alafia gbogbo. Ki ọba ki o mọ̀ pe, awa lọ si igberiko Judea si ile Ọlọrun ẹniti o tobi, ti a fi okuta nlanla kọ, a si tẹ igi si inu ogiri na, iṣẹ yi nlọ siwaju kánkán, o si nṣe rere li ọwọ wọn. Nigbana ni awa bi awọn àgba wọnni li ère, a si wi fun wọn bayi pe, Tani fun nyin li aṣẹ lati kọ́ ile yi, ati lati mọ odi yi? Awa si bère orukọ wọn pẹlu, lati mu ki o da ọ li oju, ki a le kọwe orukọ awọn enia ti iṣe olori ninu wọn. Bayi ni nwọn si fi èsi fun wa wipe, Iranṣẹ Ọlọrun ọrun on aiye li awa iṣe, awa si nkọ́ ile ti a ti kọ́ li ọdun pupọ wọnyi sẹhin, ti ọba nla kan ni Israeli ti kọ́, ti o si ti pari. Ṣugbọn nitoriti awọn baba wa mu Ọlọrun ọrun binu, o fi wọn le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babiloni ti Kaldea, ẹniti o wó ile yi palẹ, ti o si kó awọn enia na lọ si Babiloni. Ṣugbọn li ọdun ekini Kirusi ọba Babiloni, Kirusi ọba na fi aṣẹ lelẹ lati kọ́ ile Ọlọrun yi. Pẹlupẹlu ohun èlo wura ati ti fàdaka ti ile Ọlọrun ti Nebukadnessari ko lati inu tempili ti o wà ni Jerusalemu jade, ti o si mu lọ sinu tempili Babiloni, awọn na ni Kirusi ọba ko lati inu tempili Babiloni jade, a si fi wọn le ẹnikan lọwọ, orukọ ẹniti ijẹ Ṣeṣbassari, ẹniti on fi jẹ bãlẹ; On si wi fun u pe, Kó ohun èlo wọnyi lọ, ki o fi wọn si inu tempili ti o wà ni Jerusalemu, ki o si mu ki a tun kọ ile Ọlọrun yi si ipò rẹ̀. Nigbana ni Ṣeṣbassari na wá, o si fi ipilẹ ile Ọlọrun ti o wà ni Jerusalemu lelẹ: ati lati igba na ani titi di isisiyi li o ti mbẹ, ni kikọ kò si ti ipari tan. Njẹ nitorina, bi o ba wu ọba, jẹ ki a wá inu ile iṣura ọba ti o wà nibẹ ni Babiloni, bi o ba ri bẹ̃, pe Kirusi ọba fi aṣẹ lelẹ lati kọ ile Ọlọrun yi ni Jerusalemu, ki ọba ki o sọ eyi ti o fẹ fun wa nipa ọ̀ran yi.

Esr 5:6-17 Yoruba Bible (YCE)

Ohun tí Tatenai ati Ṣetari Bosenai ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn kọ sinu ìwé sí Dariusi ọba nìyí: “Sí Dariusi ọba, kí ọba ó pẹ́. “A fẹ́ kí ọba mọ̀ pé, a lọ sí agbègbè Juda, a sì dé ilé tí wọ́n kọ́ fún Ọlọrun tí ó tóbi. Òkúta ńláńlá ni wọ́n fi ń kọ́ ọ, wọ́n sì ń tẹ́ pákó sára ògiri rẹ̀. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ náà, ó sì ń tẹ̀síwájú. “A bèèrè lọ́wọ́ àwọn àgbààgbà wọn pé, ta ló fun wọn láṣẹ láti tún tẹmpili yìí kọ́ ati láti dá àwọn nǹkan inú rẹ̀ pada sibẹ. A bèèrè orúkọ wọn, kí á baà lè kọ orúkọ olórí wọn sílẹ̀ láti fi ranṣẹ sí kabiyesi. “Ìdáhùn tí wọ́n fún wa ni pé: ‘Iranṣẹ Ọlọrun ọ̀run ati ayé ni wá. Tẹmpili tí à ń tún kọ́ yìí, ọba olókìkí kan ni ó kọ́ ọ parí ní ọpọlọpọ ọdún sẹ́yìn. Ṣugbọn nítorí pé àwọn baba wa mú Ọlọrun ọ̀run bínú, ó fi wọ́n lé Nebukadinesari ọba Babiloni, ní ilẹ̀ Kalidea lọ́wọ́, òun ni ó wó tẹmpili yìí palẹ̀, tí ó sì kó àwọn eniyan ibẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Babilonia. Ṣugbọn ní ọdún kinni ìjọba Kirusi, ọba Babiloni, ó fi àṣẹ sí i pé kí wọ́n lọ tún tẹmpili náà kọ́. Ó dá àwọn ohun èlò wúrà ati ti fadaka pada, tí Nebukadinesari kó ninu ilé OLUWA ní Jerusalẹmu, lọ sí ilé oriṣa rẹ̀ ní Babiloni tẹ́lẹ̀. Gbogbo nǹkan wọnyi ni Kirusi ọba kó jáde kúrò ninu tẹmpili ní Babiloni, ó kó wọn lé Ṣeṣibasari lọ́wọ́, ẹni tí ó yàn ní gomina lórí Juda. Ó sọ fún un nígbà náà pé, “Gba àwọn ohun èèlò wọnyi, kó wọn lọ sinu tẹmpili tí ó wà ní Jerusalẹmu, kí ẹ sì tún tẹmpili náà kọ́ sí ojú ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀.” Ṣeṣibasari bá wá, ó sì fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ ní Jerusalẹmu. Láti ìgbà náà ni iṣẹ́ ti ń lọ níbẹ̀ títí di ìsinsìnyìí, kò sì tíì parí.’ “Nítorí náà, kabiyesi, tí ó bá dára lójú rẹ, jẹ́ kí wọ́n lọ wo ìwé àkọsílẹ̀ ní Babiloni bí kìí bá ṣe nítòótọ́ ni Kirusi pàṣẹ pé kí wọ́n tún ilé Ọlọrun kọ́ ní Jerusalẹmu. Lẹ́yìn náà jẹ́ kí á mọ ohun tí o fẹ́ kí á ṣe nípa ọ̀rọ̀ yìí.”

Esr 5:6-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èyí ni ẹ̀dà lẹ́tà tí Tatenai, olórí agbègbè Eufurate àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn. Àwọn olóyè ti agbègbè Eufurate, fi ránṣẹ́ sí ọba Dariusi. Ìròyìn tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i kà báyìí pé: Sí ọba Dariusi: Àlàáfíà fún un yín. Kí ọba kí ó mọ̀ pé a lọ sí ẹ̀kún Juda, sí tẹmpili Ọlọ́run tí ó tóbi. Àwọn ènìyàn náà ń kọ́ ọ pẹ̀lú àwọn òkúta ńláńlá àti pẹ̀lú fífi àwọn igi sí ara ògiri. Wọ́n ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àìsimi, ó sì ń ní ìtẹ̀síwájú kíákíá lábẹ́ ìṣàkóso wọn. A bi àwọn àgbàgbà, a sì fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún ilé OLúWA yìí kọ́ àti láti tún odi rẹ̀ mọ?” A sì tún béèrè orúkọ wọn pẹ̀lú, kí a lè kọ àwọn orúkọ àwọn olórí wọn sílẹ̀ kí ẹ ba à le mọ ọ́n. Èyí ni ìdáhùn tí wọ́n fún wa: “Àwa ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, àwa sì ń tún tẹmpili ilé OLúWA tí a ti kọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kọ́, èyí tí ọba olókìkí kan ní Israẹli kọ́, tí ó sì parí i rẹ̀. Ṣùgbọ́n nítorí tí àwọn baba wa mú Ọlọ́run ọ̀run bínú, ó fi wọ́n lé Nebukadnessari ti Kaldea, ọba Babeli lọ́wọ́, ẹni tí ó run tẹmpili OLúWA yìí tí ó sì kó àwọn ènìyàn náà padà sí Babeli. “Ṣùgbọ́n ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba Kirusi ọba Babeli, ọba Kirusi pàṣẹ pé kí a tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́. Òun tilẹ̀ kò jáde láti inú tẹmpili ní babeli fàdákà àti ohun èlò wúrà ilé Ọlọ́run, èyí tí Nebukadnessari kó láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu wá sí inú tẹmpili ní Babeli. Ọba Kirusi kó wọn fún ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Ṣeṣbassari, ẹni tí ó ti yàn gẹ́gẹ́ bí i baálẹ̀, ó sì sọ fún un pé, ‘Kó àwọn ohun èlò yìí kí o lọ, kí o sì kó wọn sí inú ilé Olúwa ní Jerusalẹmu, kí ẹ sì tún ilé Ọlọ́run kọ́ sí ipò o rẹ̀.’ “Nígbà náà ni Ṣeṣbassari náà wá, ó sí fi ìpìlẹ̀ ilé Ọlọ́run tí ó wá ní Jerusalẹmu lélẹ̀, láti ìgbà náà àní títí di ìsinsin yìí ni o ti n bẹ ní kíkọ́ ṣùgbọ́n, kò sí tí ì parí tán.” Nísinsin yìí tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí nínú ìwé ìrántí ní ilé ìṣúra ọba ní Babeli láti rí bí ọba Kirusi fi àṣẹ lélẹ̀ lóòótọ́ láti tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́ ní Jerusalẹmu. Nígbà náà jẹ́ kí ọba kó fi ìpinnu rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí ránṣẹ́ sí wa.