Esr 5:3-4
Esr 5:3-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Li akoko kanna ni Tatnai, bãlẹ ni ihahin odò, ati Ṣetar-bosnai pẹlu awọn ẹgbẹ wọn, wá si ọdọ wọn, nwọn si wi fun wọn bayi pe, Tani fun nyin li aṣẹ lati kọ́ ile yi, ati lati tun odi yi ṣe? Nigbana ni awa wi fun wọn bayi, pe, Orukọ awọn ọkunrin ti nkọ́ ile yi ti ijẹ?
Esr 5:3-4 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkókò kan náà, Tatenai, gomina agbègbè òdìkejì odò ati Ṣetari Bosenai ati gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn wá sí ọ̀dọ̀ wọn, wọ́n bi wọ́n léèrè pé: “Ta ló fun yín láṣẹ láti kọ́ tẹmpili yìí ati láti dá àwọn nǹkan inú rẹ̀ pada sibẹ? Ati pé, kí ni orúkọ àwọn tí wọ́n ń kọ́ ilé yìí?”
Esr 5:3-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní àkókò náà Tatenai, baálẹ̀ ti agbègbè Eufurate àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹgbẹgbẹ́ wọn lọ sí ọ̀dọ̀ wọn. Wọ́n sì béèrè pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún tẹmpili yìí kọ́ àti láti tún odi yìí mọ?” Wọ́n sì tún béèrè pé, “Kí ni orúkọ àwọn ọkùnrin tí ó ń kọ́ ilé yìí?”