Esr 4:4-5
Esr 4:4-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni awọn enia ilẹ na mu ọwọ awọn enia Juda rọ, nwọn si yọ wọn li ẹnu ninu kikọle na. Nwọn si bẹ̀ awọn ìgbimọ li ọ̀wẹ si wọn, lati sọ ipinnu wọn di asan, ni gbogbo ọjọ Kirusi, ọba Persia, ani titi di ijọba Dariusi, ọba Persia.
Esr 4:4-5 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni àwọn tí wọ́n ti ń gbé ilẹ̀ náà mú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá àwọn ará ilẹ̀ Juda, wọ́n sì dẹ́rùbà wọ́n, kí wọ́n má baà lè kọ́ tẹmpili náà. Wọ́n gba àwọn olùdámọ̀ràn èké tí wọ́n ń san owó fún láti da ìpinnu àwọn ará Juda rú ní gbogbo àkókò ìjọba Kirusi, ọba Pasia, títí di àkókò Dariusi, ọba Pasia.
Esr 4:4-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú ọwọ́ àwọn ènìyàn Juda rọ, wọ́n sì dẹ́rùbà wọ́n ní ti kíkọ́ ilé náà. Wọ́n gba àwọn olùdámọ̀ràn láti ṣiṣẹ́ lòdì sí wọn àti láti sọ ète wọn di asán ní gbogbo àsìkò ìjọba Kirusi ọba Persia àti títí dé ìgbà ìjọba Dariusi ọba Persia.