Esr 4:1-3
Esr 4:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI awọn ọta Juda ati Benjamini gbọ́ pe awọn ọmọ-igbekun nkọ́ tempili fun Oluwa Ọlọrun Israeli; Nigbana ni nwọn tọ̀ Serubbabeli wá, ati awọn olori awọn baba, nwọn si wi fun wọn pe, ẹ jẹ ki awa ki o ba nyin kọle, nitoriti awa nṣe afẹri Ọlọrun nyin, gẹgẹ bi ẹnyin; awa si nru ẹbọ si ọdọ rẹ̀, lati ọjọ Esarhaddoni, ọba Assuri, ẹniti o mu wa gòke wá ihinyi. Ṣugbọn Serubbabeli, ati Jeṣua ati iyokù ninu awọn olori awọn baba Israeli wi fun wọn pe, Kì iṣe fun awa pẹlu ẹnyin, lati jumọ kọ ile fun Ọlọrun wa; ṣugbọn awa tikarawa ni yio jùmọ kọle fun Oluwa Ọlọrun Israeli gẹgẹ bi Kirusi ọba, ọba Persia, ti paṣẹ fun wa
Esr 4:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà ti àwọn ọ̀tá Juda ati ti Bẹnjamini gbọ́ pé àwọn tí wọ́n ti ìgbèkùn dé ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé OLUWA Ọlọrun Israẹli, wọ́n wá sọ́dọ̀ Serubabeli, ati sọ́dọ̀ àwọn baálé baálé, wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á jọ kọ́ ọ nítorí ọ̀kan náà ni wá, Ọlọrun yín ni àwa náà ń sìn, a sì ti ń rúbọ sí i láti ìgbà ayé Esaradoni, ọba Asiria, tí ó mú wa wá síhìn-ín.” Ṣugbọn Serubabeli, Jeṣua, ati àwọn baálé baálé tí wọ́n ṣẹ́kù ní Israẹli dá wọn lóhùn pé, “A kò fẹ́ kí ẹ bá wa lọ́wọ́ sí kíkọ́ ilé OLUWA Ọlọrun wa. Àwa nìkan ni a óo kọ́ ọ gẹ́gẹ́ bí Kirusi, ọba Pasia, ti pa á láṣẹ fún wa.”
Esr 4:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí àwọn ọ̀tá Juda àti Benjamini gbọ́ wí pé àwọn ìgbèkùn tí ó padà dé ń kọ́ tẹmpili fún OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Serubbabeli àti sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àwọn ìdílé, wọ́n sì wí pé, “Jẹ́ kí a bá a yín kọ́ nítorí pé, bí i tiyín, a ń wá Ọlọ́run yín, a sì ti ń rú ẹbọ sí i láti ìgbà Esarhadoni ọba Asiria, tí ó mú wa wá sí ibi yìí.” Ṣùgbọ́n Serubbabeli, Jeṣua àti ìyókù àwọn olórí àwọn ìdílé Israẹli dáhùn pé, “Ẹ kò ní ohunkóhun pẹ̀lú wa ní kíkọ́ ilé fún Ọlọ́run wa. Àwa nìkan yóò kọ́ ọ fún OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, bí Kirusi, ọba Persia, ti pàṣẹ fún wa.”