Esr 3:9
Esr 3:9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni Jeṣua pẹlu awọn ọmọkunrin rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, Kadmieli ati awọn ọmọ rẹ̀, awọn ọmọ Juda, jumọ dide bi ẹnikanṣoṣo lati ma tọju awọn oniṣẹ ninu ile Ọlọrun; awọn ọmọ Henadadi, pẹlu awọn ọmọ wọn, ati arakunrin wọn, awọn ọmọ Lefi.
Pín
Kà Esr 3Esr 3:9 Yoruba Bible (YCE)
Jeṣua ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu àwọn ìbátan rẹ̀, ati Kadimieli pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ Juda ń ṣe alabojuto àwọn tí wọn ń kọ́ ilé Ọlọrun pẹlu àwọn ọmọ Henadadi, ati àwọn Lefi pẹlu àwọn ọmọ wọn ati àwọn ìbátan wọn.
Pín
Kà Esr 3Esr 3:9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jeṣua àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti Kadmieli àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ Juda (àwọn ìran Hodafiah) àti àwọn ọmọ Henadadi àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn arákùnrin wọn—gbogbo ará Lefi—parapọ̀ láti bojútó àwọn òṣìṣẹ́ náà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí í kíkọ́ ilé Ọlọ́run.
Pín
Kà Esr 3