Esr 3:7-9
Esr 3:7-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si fi owo fun awọn ọmọle pẹlu, ati fun awọn gbẹna-gbẹna, pẹlu onjẹ, ati ohun mimu, ati ororo, fun awọn ara Sidoni, ati fun awọn ara Tire, lati mu igi kedari ti Lebanoni wá si okun Joppa, gẹgẹ bi aṣẹ ti nwọn gbà lati ọwọ Kirusi ọba Persia. Li ọdun keji ti nwọn wá si ile Ọlọrun ni Jerusalemu, li oṣu keji, ni Serubbabeli, ọmọ Ṣealtieli bẹ̀rẹ, ati Jeṣua ọmọ Josadaki, ati iyokù awọn arakunrin wọn, awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo awọn ti o ti ìgbekun jade wá si Jerusalemu, nwọn si yan awọn ọmọ Lefi lati ẹni ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ lati ma tọju iṣẹ ile Oluwa. Nigbana ni Jeṣua pẹlu awọn ọmọkunrin rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, Kadmieli ati awọn ọmọ rẹ̀, awọn ọmọ Juda, jumọ dide bi ẹnikanṣoṣo lati ma tọju awọn oniṣẹ ninu ile Ọlọrun; awọn ọmọ Henadadi, pẹlu awọn ọmọ wọn, ati arakunrin wọn, awọn ọmọ Lefi.
Esr 3:7-9 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n fi owó sílẹ̀ fún àwọn tí wọn ń gbẹ́ òkúta ati fún àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà. Wọ́n fún àwọn ará Sidoni ati àwọn ará Tire ní oúnjẹ, ohun mímu, ati òróró; wọ́n fi ṣe pàṣípààrọ̀ fún igi kedari láti ilẹ̀ Lẹbanoni. Wọ́n ní kí wọ́n kó àwọn igi náà wá sí Jọpa ní etí òkun fún wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Kirusi, ọba Pasia pa. Ní oṣù keji ọdún keji tí wọ́n dé sí ilé Ọlọrun ní Jerusalẹmu ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà. Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, ati Jeṣua ọmọ Josadaki, ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, pẹlu àwọn arakunrin wọn yòókù, àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn tí wọ́n ti ìgbèkùn pada sí Jerusalẹmu. Wọ́n yan àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ti tó ọmọ ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, láti máa bojútó iṣẹ́ ilé OLUWA. Jeṣua ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu àwọn ìbátan rẹ̀, ati Kadimieli pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ Juda ń ṣe alabojuto àwọn tí wọn ń kọ́ ilé Ọlọrun pẹlu àwọn ọmọ Henadadi, ati àwọn Lefi pẹlu àwọn ọmọ wọn ati àwọn ìbátan wọn.
Esr 3:7-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni wọ́n fún àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ní owó, wọ́n sì tún fi oúnjẹ, ohun mímu àti òróró fún àwọn ará Sidoni àti Tire, kí wọ́n ba à le è kó igi kedari gba ti orí omi Òkun láti Lebanoni wá sí Joppa, gẹ́gẹ́ bí Kirusi ọba Persia ti pàṣẹ. Ní oṣù kejì ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n ti padà dé sí ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, Jeṣua ọmọ Josadaki àti àwọn arákùnrin yòókù (àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi àti gbogbo àwọn tí ó ti ìgbèkùn dé sí Jerusalẹmu) bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà. Wọ́n sì yan àwọn ọmọ Lefi tí ó tó ọmọ-ogun ọdún sókè láti máa bojútó kíkọ́ ilé OLúWA. Jeṣua àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti Kadmieli àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ Juda (àwọn ìran Hodafiah) àti àwọn ọmọ Henadadi àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn arákùnrin wọn—gbogbo ará Lefi—parapọ̀ láti bojútó àwọn òṣìṣẹ́ náà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí í kíkọ́ ilé Ọlọ́run.