Esr 3:7-13

Esr 3:7-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nwọn si fi owo fun awọn ọmọle pẹlu, ati fun awọn gbẹna-gbẹna, pẹlu onjẹ, ati ohun mimu, ati ororo, fun awọn ara Sidoni, ati fun awọn ara Tire, lati mu igi kedari ti Lebanoni wá si okun Joppa, gẹgẹ bi aṣẹ ti nwọn gbà lati ọwọ Kirusi ọba Persia. Li ọdun keji ti nwọn wá si ile Ọlọrun ni Jerusalemu, li oṣu keji, ni Serubbabeli, ọmọ Ṣealtieli bẹ̀rẹ, ati Jeṣua ọmọ Josadaki, ati iyokù awọn arakunrin wọn, awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo awọn ti o ti ìgbekun jade wá si Jerusalemu, nwọn si yan awọn ọmọ Lefi lati ẹni ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ lati ma tọju iṣẹ ile Oluwa. Nigbana ni Jeṣua pẹlu awọn ọmọkunrin rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, Kadmieli ati awọn ọmọ rẹ̀, awọn ọmọ Juda, jumọ dide bi ẹnikanṣoṣo lati ma tọju awọn oniṣẹ ninu ile Ọlọrun; awọn ọmọ Henadadi, pẹlu awọn ọmọ wọn, ati arakunrin wọn, awọn ọmọ Lefi. Nigbati awọn ọmọle si fi ipilẹ tempili Oluwa lelẹ, nwọn mu awọn alufa duro ninu aṣọ wọn, nwọn mu ipè lọwọ, ati awọn ọmọ Lefi, awọn ọmọ Asafu mu kimbali lọwọ, lati ma yìn Oluwa gẹgẹ bi ìlana Dafidi ọba Israeli. Nwọn si jùmọ kọrin lẹsẹsẹ lati yìn ati lati dupẹ fun Oluwa, nitoripe o ṣeun, ati pe anu rẹ̀ si duro lailai lori Israeli. Gbogbo enia si ho iho nla, nigbati nwọn nyìn Oluwa, nitoriti a fi ipilẹ ile Oluwa lelẹ. Ṣugbọn pupọ ninu awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, pẹlu awọn olori awọn baba ti iṣe alàgba, ti nwọn ti ri ile atetekọṣe, nwọn fi ohùn rara sọkun, nigbati a fi ipilẹ ile yi lelẹ li oju wọn, ṣugbọn awọn pupọ si ho iho nla fun ayọ̀: Tobẹ̃ ti awọn enia kò le mọ̀ iyatọ ariwo ayọ̀ kuro ninu ariwo ẹkun awọn enia; nitori awọn enia ho iho nla, a si gbọ́ ariwo na li okere rére.

Esr 3:7-13 Yoruba Bible (YCE)

Wọ́n fi owó sílẹ̀ fún àwọn tí wọn ń gbẹ́ òkúta ati fún àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà. Wọ́n fún àwọn ará Sidoni ati àwọn ará Tire ní oúnjẹ, ohun mímu, ati òróró; wọ́n fi ṣe pàṣípààrọ̀ fún igi kedari láti ilẹ̀ Lẹbanoni. Wọ́n ní kí wọ́n kó àwọn igi náà wá sí Jọpa ní etí òkun fún wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Kirusi, ọba Pasia pa. Ní oṣù keji ọdún keji tí wọ́n dé sí ilé Ọlọrun ní Jerusalẹmu ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà. Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, ati Jeṣua ọmọ Josadaki, ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, pẹlu àwọn arakunrin wọn yòókù, àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn tí wọ́n ti ìgbèkùn pada sí Jerusalẹmu. Wọ́n yan àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ti tó ọmọ ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, láti máa bojútó iṣẹ́ ilé OLUWA. Jeṣua ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu àwọn ìbátan rẹ̀, ati Kadimieli pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ Juda ń ṣe alabojuto àwọn tí wọn ń kọ́ ilé Ọlọrun pẹlu àwọn ọmọ Henadadi, ati àwọn Lefi pẹlu àwọn ọmọ wọn ati àwọn ìbátan wọn. Nígbà tí àwọn mọlémọlé bẹ̀rẹ̀ sí fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA lélẹ̀, àwọn alufaa gbé ẹ̀wù wọn wọ̀, wọ́n dúró pẹlu fèrè lọ́wọ́ wọn. Ìdílé Asafu, ẹ̀yà Lefi, ń lu kimbali wọn, wọ́n fí ń yin OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ètò tí Dafidi, ọba Israẹli, ti ṣe. Pẹlu orin ìyìn ati ìdúpẹ́ wọ́n ń kọrin sí OLUWA pẹlu ègbè rẹ̀ pé, “OLUWA ṣeun, ìfẹ́ rẹ̀ sí Israẹli dúró títí lae.” Gbogbo àwọn eniyan hó ìhó ìyìn sí OLUWA, nítorí pé wọ́n fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA lélẹ̀. Ṣugbọn ọpọlọpọ àwọn alufaa, àwọn ẹ̀yà Lefi, ati àwọn olórí ìdílé, àwọn àgbàlagbà tí wọ́n gbọ́njú mọ ilé OLUWA ti tẹ́lẹ̀ sọkún, wọ́n kígbe sókè nígbà tí wọ́n rí bí a ti ń fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA náà lélẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn mìíràn hó fún ayọ̀. Kò sí ẹni tí ó lè mọ ìyàtọ̀ láàrin ariwo ẹkún ati ti ayọ̀ nítorí pé, gbogbo wọn ń kígbe sókè, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn eniyan sì gbọ́ igbe wọn ní ọ̀nà jíjìn réré.

Esr 3:7-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni wọ́n fún àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ní owó, wọ́n sì tún fi oúnjẹ, ohun mímu àti òróró fún àwọn ará Sidoni àti Tire, kí wọ́n ba à le è kó igi kedari gba ti orí omi Òkun láti Lebanoni wá sí Joppa, gẹ́gẹ́ bí Kirusi ọba Persia ti pàṣẹ. Ní oṣù kejì ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n ti padà dé sí ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, Jeṣua ọmọ Josadaki àti àwọn arákùnrin yòókù (àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi àti gbogbo àwọn tí ó ti ìgbèkùn dé sí Jerusalẹmu) bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà. Wọ́n sì yan àwọn ọmọ Lefi tí ó tó ọmọ-ogun ọdún sókè láti máa bojútó kíkọ́ ilé OLúWA. Jeṣua àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti Kadmieli àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ Juda (àwọn ìran Hodafiah) àti àwọn ọmọ Henadadi àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn arákùnrin wọn—gbogbo ará Lefi—parapọ̀ láti bojútó àwọn òṣìṣẹ́ náà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí í kíkọ́ ilé Ọlọ́run. Nígbà tí àwọn ọ̀mọ̀lé gbé ìpìlẹ̀ ilé OLúWA kalẹ̀, àwọn àlùfáà nínú aṣọ iṣẹ́ àlùfáà wọn pẹ̀lú fèrè, àti àwọn ará Lefi (àwọn ọmọ Asafu) pẹ̀lú símbálì, dúró ní ipò wọn láti yin OLúWA, bí Dafidi ọba Israẹli ti fi lélẹ̀. Pẹ̀lú ìyìn àti ọpẹ́ ni wọ́n kọrin sí OLúWA: “Ó dára; ìfẹ́ rẹ̀ sí Israẹli dúró títí láé.” Gbogbo àwọn ènìyàn sì fi ohùn ariwo ńlá yin OLúWA, nítorí tí a ti fi ìpìlẹ̀ ilé OLúWA lélẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ lára àwọn àgbà àlùfáà àti àwọn ará Lefi àti àwọn olórí ìdílé, tí ó ti rí tẹmpili OLúWA ti tẹ́lẹ̀, wọ́n sọkún kíkorò nígbà tí wọ́n rí ìpìlẹ̀ tẹmpili OLúWA yìí tí wọ́n fi lélẹ̀, nígbà tí ọ̀pọ̀ kígbe fún ayọ̀. Kò sí ẹni tí ó le mọ ìyàtọ̀ láàrín igbe ayọ̀ àti ẹkún, nítorí tí ariwo àwọn ènìyàn náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́. Wọ́n sì gbọ́ igbe náà ní ọ̀nà jíjìn réré.