Esr 10:1-4
Esr 10:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI Esra ti gba adura, ti o si jẹwọ pẹlu ẹkún ati idojubolẹ niwaju ile Ọlọrun, ijọ enia pupọ kó ara wọn jọ si ọdọ rẹ̀ lati inu Israeli jade, ati ọkunrin ati obinrin ati ọmọ wẹwẹ: nitori awọn enia na sọkun gidigidi. Ṣekaniah ọmọ Jehieli, lati inu awọn ọmọ Elamu dahùn o si wi fun Esra pe, Awa ti ṣẹ̀ si Ọlọrun wa, ti awa ti mu ajeji obinrin lati inu awọn enia ilẹ na: sibẹ, ireti mbẹ fun Israeli nipa nkan yi. Njẹ nitorina ẹ jẹ ki awa ki o ba Ọlọrun wa da majẹmu, lati kọ̀ gbogbo awọn obinrin na silẹ, ati iru awọn ti nwọn bi gẹgẹ bi ìmọ (Esra) oluwa mi, ati ti awọn ti o wariri si aṣẹ Ọlọrun wa: ki awa ki o si mu u ṣẹ gẹgẹ bi ofin na. Dide! nitori ọran tirẹ li eyi: awa pãpã yio wà pẹlu rẹ, mu ọkàn le ki o si ṣe e.
Esr 10:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Bí Ẹsira ti ń gbadura, tí ó ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, tí ó ń sọkún, tí ó sì dojúbolẹ̀ níwájú ilé Ọlọrun, àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí dúró yí i ká, tọmọde, tàgbà, tọkunrin, tobinrin. Àwọn náà ń sọkún gan-an. Ṣekanaya, ọmọ Jehieli, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Elamu bá sọ fún Ẹsira pé: “A ti hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí Ọlọrun wa, nítorí a ti lọ fẹ́ aya láàrin àwọn ẹ̀yà tí wọ́n yí wa ká, sibẹsibẹ, ìrètí ń bẹ fún àwọn ọmọ Israẹli. Nítorí náà, jẹ́ kí á bá Ọlọrun wa dá majẹmu pé a óo lé àwọn obinrin àjèjì wọnyi lọ pẹlu àwọn ọmọ wọn gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwọ, oluwa mi, ati àwọn tí wọ́n bẹ̀rù òfin Ọlọrun wa wí, kí á ṣe é bí òfin ti wí. Ọwọ́ rẹ ni ọ̀rọ̀ yí wà; dìde nílẹ̀ kí o ṣe é. A wà lẹ́yìn rẹ, nítorí náà ṣe ọkàn gírí.”
Esr 10:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Esra ń gbàdúrà tí ó sì ń jẹ́wọ́, ti ó ń sọkún ti ó sì ń gbárayílẹ̀ níwájú ilé Ọlọ́run, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Israẹli ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ọmọdé pagbo yí i ká. Àwọn náà ń sọkún kíkorò. Nígbà náà ni Ṣekaniah ọmọ Jehieli, ọ̀kan lára ìran Elamu, sọ fún Esra pé, Àwa ti jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa nípa fífẹ́ àwọn obìnrin àjèjì láàrín àwọn ènìyàn tí ó wà yí wa ká. Ṣùgbọ́n síbẹ̀ náà, ìrètí sì wà fún Israẹli Ní ṣinṣin yìí, ẹ jẹ́ kí a dá májẹ̀mú níwájú Ọlọ́run wa láti lé àwọn obìnrin yìí àti àwọn ọmọ wọn lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn Esra olúwa mi àti ti àwọn tí ó bẹ̀rù àṣẹ OLúWA Ọlọ́run wa. Ẹ jẹ́ kí a ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin. Dìde, nítorí, ọ̀rọ̀ tìrẹ ni èyí. Gbogbo wà yóò wá pẹ̀lú rẹ, mú ọkàn le kí o sì ṣe é.