Esr 1:5-11
Esr 1:5-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni awọn olori awọn baba Juda ati Benjamini dide, ati awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, pẹlu gbogbo awọn ẹniti Ọlọrun rú ẹmi wọn soke, lati goke lọ, lati kọ́ ile OLUWA ti o wà ni Jerusalemu. Gbogbo awọn ti o wà li agbegbe wọn si fi ohun-èlo fadaka ràn wọn lọwọ, pẹlu wura, pẹlu ẹrù ati pẹlu ẹran-ọ̀sin, ati pẹlu ohun iyebiye, li aika gbogbo ọrẹ atinuwa. Kirusi ọba si ko ohun èlo ile OLUWA jade, ti Nebukadnessari ti ko jade lọ lati Jerusalemu, ti o si fi sinu ile ọlọrun rẹ̀; Kirusi ọba Persia si ko wọnyi jade nipa ọwọ Mitredati, oluṣọ iṣura, o si ka iye wọn fun Ṣeṣbassari (Serubbabeli) bãlẹ Juda. Iye wọn si li eyi: ọgbọn awo-pọ̀kọ wura, ẹgbẹrun awo-pọ̀kọ fadaka, ọbẹ mọkandilọgbọn, Ọgbọn ago wura, ago fadaka iru ekeji, irinwo o le mẹwa, ohun èlo miran si jẹ ẹgbẹrun. Gbogbo ohun-èlo wura ati ti fadaka jẹ ẹgbẹtadilọgbọn. Gbogbo wọnyi ni Ṣeṣbassari mu goke wá pẹlu awọn igbekun ti a mu goke lati Babiloni wá si Jerusalemu.
Esr 1:5-11 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn olórí ninu ìdílé ẹ̀yà Juda ati ẹ̀yà Bẹnjamini, ati àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi sì dìde, pẹlu àwọn tí Ọlọrun ti fi sí lọ́kàn láti tún ilé OLUWA tí ó wà ní Jerusalẹmu kọ́. Àwọn aládùúgbò wọn fi ohun èlò fadaka ati ti wúrà, ati dúkìá, ati ẹran ọ̀sìn, ati àwọn nǹkan olówó iyebíye ràn wọ́n lọ́wọ́, yàtọ̀ sí àwọn ọrẹ àtinúwá. Kirusi ọba náà kó àwọn ohun èlò inú ilé OLUWA jáde, tí Nebukadinesari kó wá sinu àwọn ilé oriṣa rẹ̀, láti Jerusalẹmu. Kirusi ọba fún Mitiredati, akápò ìjọba rẹ̀ ní àṣẹ láti kó wọn síta, ó sì kà wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan fún Ṣeṣibasari, olórí ẹ̀yà Juda. Iye àwọn nǹkan náà nìyí: Ẹgbẹrun kan (1,000) àwo wúrà, ẹgbẹrun kan (1,000) àwo fadaka, àwo turari mọkandinlọgbọn; ọgbọ̀n àwokòtò wúrà, ẹgbaa ó lé irinwo ati mẹ́wàá (2,410) àwo fadaka kéékèèké, ẹgbẹrun (1,000) oríṣìíríṣìí ohun èlò mìíràn. Àpapọ̀ àwọn ohun èlò wúrà ati fadaka yìí jẹ́ ẹẹdẹgbaata ó lé irinwo (5,400). Ṣeṣibasari kó wọn lọ́wọ́ bí àwọn tí wọn kúrò ní oko ẹrú Babiloni ti ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu.
Esr 1:5-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà àwọn olórí ìdílé Juda àti Benjamini àti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi—olúkúlùkù ẹni tí Ọlọ́run ti fọwọ́ tọ́ ọkàn rẹ̀—múra láti gòkè lọ láti kọ ilé OLúWA ní Jerusalẹmu. Gbogbo àwọn aládùúgbò wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun èlò ti fàdákà àti wúrà, pẹ̀lú onírúurú ohun ìní àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn iyebíye, ní àfikún si gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá. Ní àfikún, ọba Kirusi mú àwọn ohun èlò tí ó jẹ́ ti ilé OLúWA jáde wá, tí Nebukadnessari ti kó lọ láti Jerusalẹmu tí ó sì ti kó sí ilé òrìṣà rẹ̀. Kirusi ọba Persia pàṣẹ fún Mitredati olùṣọ́ ilé ìṣúra láti kó wọn jáde, ó sì kà wọ́n fún Ṣeṣbassari ìjòyè Juda. Èyí ni iye wọn: Ọgbọ̀n àwo wúrà 30 Ẹgbẹ̀rún àwo fàdákà 1,000 Àwo ìrúbọ fàdákà mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n 29 Ọgbọ̀n àdému wúrà 30 Irínwó ó-lé-mẹ́wàá oríṣìí àdému fàdákà mìíràn 410 Ẹgbẹ̀rún kan àwọn ohun èlò mìíràn 1,000 Gbogbo ohun èlò wúrà àti ti fàdákà ní àpapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó-lé-irínwó (5,400).