Esek 8:11-12
Esek 8:11-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Adọrin ọkunrin ninu awọn agbà ile Israeli si duro niwaju wọn, Jaasania ọmọ Ṣafani si duro lãrin wọn, olukuluku pẹlu awo turari lọwọ rẹ̀; ẹ̃fin ṣiṣu dùdu ti turari si goke lọ. Nigbana li o si wi fun mi pe, Ọmọ enia iwọ ri ohun ti awọn agbà ile Israeli nṣe li okunkùn, olukuluku ninu iyará oriṣa tirẹ̀? nitori nwọn wipe, Oluwa kò ri wa; Oluwa ti kọ̀ aiye silẹ.
Esek 8:11-12 Yoruba Bible (YCE)
Mo sì rí aadọrin ninu àwọn àgbààgbà àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n dúró níwájú àwọn oriṣa wọnyi, Jaasanaya ọmọ Ṣafani dúró láàrin wọn. Olukuluku mú ohun tí ó fi ń sun turari lọ́wọ́, èéfín turari sì ń fẹ́ lọ sókè. OLUWA tún bi mí pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí àwọn àgbààgbà ilé Israẹli ń ṣe ninu òkùnkùn? Ṣé o rí ohun tí olukuluku ń ṣe ninu yàrá tí ó kún fún àwòrán ère oriṣa? Wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA kò rí wa, ó ti kọ ilẹ̀ wa sílẹ̀.’ ”
Esek 8:11-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Níwájú wọn ni àádọ́rin (70) ọkùnrin tó jẹ́ àgbàgbà ilé Israẹli dúró sí, Jaaṣaniah ọmọ Ṣafani sì dúró sí àárín wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì mú àwo tùràrí lọ́wọ́, òórùn sì ń tú jáde. Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o ti rí ohun tí àwọn àgbàgbà ilé Israẹli ń ṣe nínú òkùnkùn, olúkúlùkù ní yàrá òrìṣà rẹ̀? Wọ́n ní, ‘OLúWA kò rí wa; OLúWA ti kọ̀ ilé náà sílẹ̀.’ ”