Esek 6:9
Esek 6:9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn ti o bọ́ ninu nyin yio si ranti mi, lãrin awọn orilẹ-ède nibiti nwọn o gbe dì wọn ni igbekun lọ, nitoriti mo ti fọ́ ọkàn agbere wọn ti o ti lọ kuro lọdọ mi, ati pẹlu oju wọn, ti nṣagbere lọ sọdọ oriṣa wọn: nwọn o si sú ara wọn nitori ìwa ibi ti nwọn ti hù ninu gbogbo irira wọn.
Esek 6:9 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà, àwọn tí wọ́n sá àsálà ninu yín yóo ranti mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí a bá kó wọn ní ìgbèkùn lọ, nígbà tí mo bá mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn tí ó ń mú wọn kọ̀ mí sílẹ̀ kúrò, tí mo bá sì fọ́ ojú tí wọ́n fi ń ṣe àgbèrè tẹ̀lé àwọn oriṣa wọn. Ojú ara wọn yóo tì wọ́n nítorí ibi tí wọ́n ṣe, ati nítorí gbogbo ìwà ìríra wọn.
Esek 6:9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ti ó bọ́ nínú yin yóò sì rántí mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè níbi tí wọn yóò dìwọ́n ní ìgbèkùn lọ, nítorí wọ́n yóò máa rántí mi bí wọ́n ti bà mí lọ́kàn jẹ́ nípa àgbèrè wọn, tí ó yà wọ́n kúrò lọ́dọ̀ mi àti nípa ojú wọn tí ó ṣàfẹ́rí àwọn òrìṣà. Wọn yóò sì ṣú ara wọn nítorí ìwà ibi tí wọ́n ti hù nípa gbogbo ìríra wọn.