Esek 47:1-12

Esek 47:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si mu mi padà wá si ibi ilẹkùn ile na; si kiyesi i, omi ntù jade lati abẹ iloro ile na nihà ila-õrun: nitori iwaju ile na wà ni ila-õrun, omi si nwalẹ lati abẹ apa ọtun ile na, ni gusu pẹpẹ. O si mu mi jade ni ọ̀na ẹnu-ọ̀na ihà ariwa, o si mu mi yi wá ọ̀na ode si ẹnu-ọ̀na ode ni ọ̀na ti o kọjusi ila-õrun; si kiyesi i, omi ṣàn jade lati ihà ọtun. Nigbati ọkunrin na jade sihà ila-õrun, pẹlu okùn kan lọwọ rẹ̀, o si wọ̀n ẹgbẹrun igbọnwọ, o si mu mi là omi na ja; omi na si de kókosẹ̀. O tun wọ̀n ẹgbẹrun, o si mu mi là omi na ja; omi na si de ẽkun. O si wọ̀n ẹgbẹrun, o si mu mi là a ja; omi si de ẹgbẹ́. O si wọ̀n ẹgbẹrun; odò ti nkò le wọ́: nitori omi ti kún, omi ilúwẹ, odò ti kò ṣe rekọja. O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, Iwọ ri yi? O si mu mi wá, o si mu mi pada wá si bèbe odò na. Nigbati mo pada, si kiyesi i, igi pupọ̀pupọ̀ wà ni ihà ihin ati ni ihà ọhun li eti odò na. O si wi fun mi pe, Omi wọnyi ntú jade sihà ilẹ ila-õrun, nwọn si nsọkalẹ lọ si pẹ̀tẹlẹ, nwọn si wọ̀ okun lọ: nigbati a si mu wọn wọ̀ inu okun, a si mu omi wọn lara dá. Yio si ṣe pe, ohunkohun ti o ba wà lãye ti nrakò, nibikibi ti odò mejeji ba de, yio wà lãye: ọ̀pọlọpọ ẹja yio si de, nitori omi wọnyi yio de ibẹ̀: a o si mu wọn lara dá; ohun gbogbo yio si yè nibikibi ti odò na ba de. Yio si ṣe pe, Awọn apẹja yio duro lori rẹ̀ lati Engedi titi de Eneglaimu; nwọn o jẹ ibi lati nà àwọn si; ẹja wọn o dabi iru wọn, bi ẹja okun-nla, lọpọlọpọ. Ṣugbọn ibi ẹrẹ̀ rẹ̀ ati ibi irà rẹ̀ li a kì o mu laradá; a o fi nwọn fun iyọ̀. Ati lẹba odò ni eti rẹ̀, ni ihà ihin ati ni ihà ọhun, ni gbogbo igi jijẹ yio hù, ti ewe rẹ̀ kì yio rọ, ti eso rẹ̀ kì yio si run: yio ma so eso titun rẹ̀ li oṣù rẹ̀, nitori omi wọn lati ibi mimọ́ ni nwọn ti ntú jade: eso rẹ̀ yio si jẹ fun jijẹ, ati ewe rẹ̀ fun imunilaradá.

Esek 47:1-12 Yoruba Bible (YCE)

Ọkunrin náà bá mú mi pada wá sí ẹnu ọ̀nà Tẹmpili, mo sì rí i tí omi kan ń sun láti abẹ́ ìlẹ̀kùn àbájáde ó ń ṣàn lọ sí ìhà ìlà oòrùn, ìhà ìlà oòrùn ni tẹmpili kọjú sí. Omi náà ń ṣàn láti apá gúsù ibi ìlẹ̀kùn àbájáde tí ó wà ni ìhà gúsù pẹpẹ ìrúbọ. Lẹ́yìn náà ó mú mi gba ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá jáde, ó sì mú mi yípo ní ìta títí tí mo fi dé ẹnu ọ̀nà àbájáde tí ó kọjú sí ìlà oòrùn. Odò kékeré kan ń ṣàn jáde láti ìhà gúsù. Ọkunrin náà lọ sí apá ìhà ìlà oòrùn, ó mú okùn ìwọ̀n kan lọ́wọ́. Ó fi wọn ẹgbẹrun igbọnwọ, (mita 450). Ó sì mú mi la odò kan tí ó mù mí dé kókósẹ̀ kọjá. Ó tún wọn ẹgbẹrun igbọnwọ (mita 450) mìíràn sí ìsàlẹ̀, ó sì mú mi la odò náà kọjá: odò yìí sì mù mí dé orúnkún. Ọkunrin náà tún wọn ẹgbẹrun igbọnwọ (mita 450) mìíràn sí ìsàlẹ̀, ó tún mú mi la odò náà kọjá: ó sì mù mí dé ìbàdí. Nígbà tí ó yá, ó tún wọn ẹgbẹrun igbọnwọ (mita 450), mìíràn sí ìsàlẹ̀, odò náà jìn ju ohun tí mo lè là kọjá lọ, nítorí pé ó ti kún sí i, ó jìn tó ohun tí eniyan lè lúwẹ̀ẹ́ ninu rẹ̀. Ó kọjá ohun tí eniyan lè là kọjá. Ọkunrin náà bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, ṣé o rí nǹkan?” Nígbà náà ni ó mú mi gba etí odò náà pada. Bí mo ṣe ń pada bọ̀, mo rí ọpọlọpọ igi ní bèbè kinni keji odò náà. Ó ní, “Omi yìí ń ṣàn lọ sí Araba, ní ìhà ìlà oòrùn, nígbà tí ó bá sì ṣàn wọ inú òkun, omi inú òkun, yóo di omi tí ó mọ́ gaara. Ọpọlọpọ ohun ẹlẹ́mìí yóo wà ní ibikíbi tí omi náà bá ti ṣàn kọjá. Ẹja yóo pọ̀ ninu rẹ̀; nítorí pé omi yìí ṣàn lọ sí inú òkun, omi tí ó wà níbẹ̀ yóo di mímọ́ gaara, ohunkohun tí ó bá sì wà ní ibi tí odò yìí bá ti ṣàn kọjá yóo yè. Àwọn apẹja yóo dúró létí òkun láti Engedi títí dé Enegilaimu, ibẹ̀ yóo di ibi tí wọn yóo ti máa na àwọ̀n wọn sá sí. Oríṣìíríṣìí ẹja ni yóo wà níbẹ̀ bí ẹja inú Òkun Ńlá. Ṣugbọn ibi ẹrọ̀fọ̀ ati àbàtà rẹ̀ kò ní di mímọ́ gaara, iyọ̀ ni yóo wà níbẹ̀. Oríṣìíríṣìí igi eléso yóo hù ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji odò náà: ewé àwọn igi náà kò ní rọ, bẹ́ẹ̀ ni èso wọn kò ní tán. Lóṣooṣù ni wọn yóo máa so èso tuntun nítorí pé láti inú tẹmpili ni omi rẹ̀ yóo ti máa sun jáde wá. Èso wọn yóo wà fún jíjẹ, ewé wọn yóo sì wà fún ìwòsàn.”

Esek 47:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọkùnrin náà mú mi padà lọ sí àbáwọlé tẹmpili náà, mo sì rí omi tí ó ń tú jáde láti abẹ́ ìloro tẹmpili náà sí apá ìhà ìlà-oòrùn (nítorí tẹmpili náà dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn) Omi náà ń tú jáde sí ìsàlẹ̀ láti abẹ́, ní ìhà gúúsù tẹmpili náà, ní ìhà gúúsù pẹpẹ. Ó wá mú mi gba ojú ọ̀nà àríwá jáde, ó sì mú mi yí ìta ojú ọ̀nà ìta tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn, omi náà sì ń sàn láti ìhà gúúsù wá. Bí ọkùnrin náà ti lọ sí apá ìhà ìlà-oòrùn pẹ̀lú okùn wíwọ̀n nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀, ó wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́, ó sì mú mi gba ibi odò kan tí kò jì jù kókósẹ̀ lọ. Ó sì wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ó sì mú mi gba ibi odò tí ó jì ní ìwọ̀n orúnkún. Ó tún wọn ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ó sì mú mi gba odò tí ó dé ìbàdí. Ó wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ṣùgbọ́n nísinsin yìí odò tí ń kò lè kọjá rẹ̀ ni, Nítorí pé odò tí ó kún, ó sì jì tó èyí tí wọ́n le lúwẹ̀ẹ́ nínú rẹ̀ odò tí ẹnikẹ́ni kò le dá kọjá ni. Ó bi mí léèrè pé: “Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ o rí èyí?” Lẹ́yìn náà, ó mú mi padà sí etí odò. Nígbà tí mo dé ibẹ̀, mo rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì odò. Ó sọ fún mi pé, “Odò yìí ń tú jáde sí ìhà ìlà-oòrùn, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì wọ inú Òkun lọ, a sì mú omi wọn láradá. Àwọn ohun alààyè tí ó ń rákò yóò máa gbé ní ibikíbi tí odò ti ń sàn. Ẹja yóò pọ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀, nítorí pé odò ń sàn síbẹ̀, ó sì mú kí omi iyọ̀ tutù nini; nítorí náà níbi tí omi ti ń sàn, gbogbo nǹkan ni yóò wà ni ààyè. Àwọn apẹja yóò dúró ní etí bèbè odò; láti En-Gedi títí dé En-Eglaimu ààyè yóò wa láti tẹ́ àwọ̀n wọn sílẹ̀. Oríṣìíríṣìí ẹja ni yóò wà gẹ́gẹ́ bí ẹja omi Òkun ńlá. Ṣùgbọ́n ẹrẹ̀ àti àbàtà kò ní tòrò; àwa yóò fi wọn sílẹ̀ fún iyọ̀. Àwọn igi eléso ní oríṣìíríṣìí ni yóò máa hù ní bèbè odò ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún. Ewé wọn kì yóò sì rọ, bẹ́ẹ̀ ní èso wọn kì yóò run, wọn yóò máa ṣe èso tuntun rẹ̀ ní oṣù nítorí pé omi láti ibi mímọ́ ń sàn sí wọn. Èso wọn yóò sì jẹ́ fún jíjẹ àti ewé wọn fún ìwòsàn.”