Esek 39:1-24
Esek 39:1-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORINA, iwọ ọmọ enia, sọtẹlẹ si Gogu, si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiye si i, emi dojukọ́ ọ, iwọ Gogu, olori ọmọ-alade Meṣeki ati Tubali: Emi o si dá ọ padà, emi o si dári rẹ, emi o si mu ọ goke wá lati ihà ariwa, emi o si mu ọ wá sori oke giga Israeli: Emi o si lù ọrun rẹ kurò li ọwọ́ osì rẹ, emi o si mu ọfà rẹ bọ kuro lọwọ ọtun rẹ. Iwọ o ṣubu lori òke giga Israeli, iwọ, ati gbogbo awọn ogun rẹ, ati awọn enia ti o wà pẹlu rẹ: emi o fi ọ fun ẹiyẹ ọdẹ onirũru iyẹ, ati ẹranko igbẹ lati pa jẹ. Iwọ o ṣubu ni gbangba oko: nitori emi li o sọ ọ, ni Oluwa Ọlọrun wi. Emi o si rán iná si Magogu, ati sãrin awọn ti ngbe erekuṣu laibẹ̀ru; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa. Emi o si sọ orukọ mimọ́ mi di mimọ̀ lãrin enia mi Israeli; emi kì yio si jẹ ki nwọn bà orukọ mimọ́ mi jẹ mọ: awọn orilẹ-ède yio si mọ̀ pe emi li Oluwa, Ẹni-Mimọ́ ni Israeli. Kiye si i, o ti de, a si ti ṣe e; ni Oluwa Ọlọrun wi, eyi ni ọjọ ti emi ti sọ. Awọn ti o si ngbe ilu Israeli yio jade lọ, nwọn o si fi ohun ihamọra wọnni jona ati asa ati apata, ọrun ati ọfà, kùmọ ati ọ̀kọ; nwọn o si fi iná sun wọn li ọdun meje: Nwọn kì yio lọ rù igi lati inu oko wá, bẹ̃ni nwọn kì yio ke igi lulẹ lati inu igbẹ́ wá; nitori ohun ihamọra ni nwọn ti fi daná; nwọn o si ko awọn ti o ko wọn, nwọn o si dọdẹ awọn ti o dọdẹ wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi. Yio si ṣe li ọjọ na, emi o fi ibikan fun Gogu nibẹ fun iboji ni Israeli, afonifoji awọn èro ni gabasi okun; on si pa awọn èro ni ẹnu mọ: nibẹ ni nwọn o gbe sin Gogu ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ si: nwọn o si pè e ni, Afonifoji Hamon-gogu. Oṣù meje ni ile Israeli yio si ma fi sin okú wọn, ki nwọn ba le sọ ilẹ na di mimọ́. Gbogbo enia ilẹ na ni yio si sin wọn: yio si jẹ okiki fun wọn li ọjọ ti a o yìn mi logo, ni Oluwa Ọlọrun wi. Nwọn o si yà awọn ọkunrin sọtọ ti yio ma fi ṣe iṣẹ iṣe, lati ma rìn ilẹ na ja lati lọ isin awọn erò ti o kù lori ilẹ, lati sọ ọ di mimọ́: lẹhin oṣù meje nwọn o ma wá kiri. Awọn èro ti nlà ilẹ na kọja, nigbati ẹnikan ba ri egungun enia kan, yio sàmi kan si ẹba rẹ̀, titi awọn asinku yio fi sin i si afonifoji Hamon-gogu. Orukọ ilu na pẹlu yio si jẹ Hamona. Bayi ni nwọn o si sọ ilẹ na di mimọ́. Ati iwọ, ọmọ enia, bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Sọ fun olukuluku ẹiyẹ abiyẹ́, ati fun olukuluku ẹranko igbẹ, pe, Ẹ ko ara nyin jọ, ki ẹ si wá: ẹ gbá ara nyin jọ ni ihà gbogbo si ẹbọ mi ti emi rú fun nyin, ani irubọ nla lori oke giga Israeli, ki ẹnyin ba le jẹ ẹran, ki ẹ si mu ẹjẹ. Ẹnyin o jẹ ẹran-ara awọn alagbara, ẹnyin o si mu ẹjẹ awọn ọmọ-alade aiye, ti agbò, ti ọdọ agutan, ati ti obukọ, ti akọ malũ, gbogbo wọn abọpa Baṣani. Ẹ o si jẹ ọra li ajẹyo, ẹ o si mu ẹjẹ li amupara, lati inu ẹbọ mi ti mo ti rú fun nyin. Bayi li a o fi ẹṣin ati ẹlẹṣin bọ́ nyin yo lori tabili mi, pẹlu awọn alagbara, ati gbogbo awọn ologun, ni Oluwa Ọlọrun wi. Emi o si gbe ogo mi kalẹ lãrin awọn keferi, gbogbo awọn keferi yio si ri idajọ mi ti mo ti ṣe, ati ọwọ́ mi ti mo ti fi le wọn. Ile Israeli yio si mọ̀ pe, Emi li Oluwa Ọlọrun wọn lati ọjọ na lọ titi. Awọn keferi yio si mọ̀ pe Israeli lọ si igbekùn nitori aiṣedẽde wọn: nitoriti nwọn ti ṣọ̀tẹ si mi, nitorina ni mo ṣe fi oju mi pamọ kuro lọdọ wọn, ti mo si fi wọn le awọn ọta wọn lọwọ: gbogbo wọn si ti ipa idà ṣubu. Gẹgẹ bi aimọ́ wọn, ati gẹgẹ bi irekọja wọn ni mo ṣe si wọn, mo si fi oju mi pamọ́ kuro lọdọ wọn.
Esek 39:1-24 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA Ọlọrun ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, fi àsọtẹ́lẹ̀ bá Gogu wí, sọ fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘Mo lòdì sí ọ́, ìwọ Gogu, ìwọ tí o jẹ́ olórí Meṣeki ati Tubali. N óo yí ọ pada, n óo lé ọ siwaju, n óo mú ọ wá láti òpin ìhà àríwá, o óo wá dojú kọ àwọn òkè Israẹli. Lẹ́yìn náà, n óo gbọn ọrun rẹ dànù lọ́wọ́ òsì rẹ; n óo sì gbọn ọfà bọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ. Ìwọ, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ, ati àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ yóo kú lórí àwọn òkè Israẹli. N óo fi yín ṣe oúnjẹ fún oniruuru àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko burúkú. Ninu pápá tí ó tẹ́jú ni ẹ óo kú sí; èmi OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo rọ òjò iná lé Magogu lórí, ati àwọn tí wọn ń gbé láìléwu ní etí òkun, wọn yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA. N óo sọ orúkọ mímọ́ mi di mímọ̀ láàrin àwọn eniyan mi àwọn ọmọ Israẹli, n kò ní jẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo sì mọ̀ pé èmi OLUWA, ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.’ ” OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! Ọjọ́ tí mo ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bọ̀, yóo dé. Àwọn ará ìlú Israẹli yóo tú síta, wọn yóo dáná sun àwọn ohun ìjà ogun: apata ati asà, ọrun ati ọfà, àáké ati ọ̀kọ̀. Ọdún meje ni wọn yóo fi dáná sun wọ́n. Fún ọdún meje yìí, ẹnìkan kò ní ṣẹ́ igi ìdáná lóko, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní gé igi ninu igbó kí wọ́n tó dáná; ohun ìjà ogun ni wọn yóo máa fi dáná. Wọn yóo kó ẹrù àwọn tí wọ́n ti kó wọn lẹ́rù rí; wọn yóo fi ogun kó àwọn ìlú tí wọ́n ti fi ogun kó wọn rí. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA ní, “Tí ó bá di ìgbà náà, n óo fún Gogu ní ibi tí wọn yóo sin ín sí ní Israẹli, àní àfonífojì àwọn arìnrìnàjò tí ó wà ní ìlà oòrùn Òkun Iyọ̀. Yóo dínà mọ́ àwọn arìnrìnàjò nítorí níbẹ̀ ni a óo sin Gogu ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ sí. A óo sì máa pè é ní àfonífojì Hamoni Gogu. Oṣù meje ni yóo gba àwọn ọmọ Israẹli láti sin òkú wọn, kí wọ́n baà lè fọ ilẹ̀ náà mọ́. Gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà ni yóo sin wọ́n, wọn óo sì gbayì ní ọjọ́ náà, nígbà tí mo bá fi ògo mi hàn. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn oṣù meje wọn yóo yan àwọn kan tí wọn óo la ilẹ̀ náà já, tí wọn óo máa wá òkú tí ó bá kù nílẹ̀, tí wọn óo sì máa sin wọ́n kí wọ́n lè sọ ilẹ̀ náà di mímọ́. Bí ẹnìkan ninu àwọn tí ń wá òkú kiri bá rí egungun eniyan níbìkan, yóo fi àmì sibẹ títí tí àwọn tí ń sin òkú yóo fi wá sin ín ní àfonífojì Hamoni Gogu. Ìlú kan yóo wà níbẹ̀ tí yóo máa jẹ́ Hamoni. Bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo ṣe fọ ilẹ̀ náà mọ́.” OLUWA Ọlọrun ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, ké pe oniruuru ẹyẹ ati gbogbo ẹranko igbó, kí o sọ fún wọn pé, ‘Ẹ gbá ara yín jọ, kí ẹ máa bọ̀ láti gbogbo àyíká tí ẹ wà. Ẹ wá sí ibi ẹbọ ńlá tí mo fẹ́ ṣe fun yín lórí àwọn òkè Israẹli. Ẹ óo jẹ ẹran, ẹ óo sì mu ẹ̀jẹ̀. Ẹ óo jẹ ẹran ara àwọn akikanju, ẹ óo sì mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ọba ilẹ̀ ayé, bíi ti àgbò, ati ọ̀dọ́ aguntan, ati ewúrẹ́ ati àwọn mààlúù rọ̀bọ̀tọ̀ Baṣani. Ẹ óo jẹ ọ̀rá ní àjẹyó, ẹ óo sì mu ẹ̀jẹ̀ ní àmuyó ní ibi àsè tí n óo sè fun yín. Ẹ óo jẹ ẹṣin ati àwọn tí wọn ń gùn wọ́n, àwọn alágbára ati oríṣìíríṣìí àwọn ọmọ ogun níbi àsè tí n óo sè fun yín.’ Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “N óo fi ògo mi hàn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo wọn ni yóo sì rí irú ẹjọ́ tí mo dá wọn ati irú ìyà tí mo fi jẹ wọ́n. Láti ìgbà náà lọ, àwọn ọmọ Israẹli óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli dá tí wọ́n fi di ẹni tí ó lọ sí ìgbèkùn, ati pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi ni mo ṣe dijú sí wọn, tí mo fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, tí wọ́n sì fi idà pa wọ́n. Bí àìmọ́ ati ẹ̀ṣẹ̀ wọn ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni mo fìyà jẹ wọ́n tó, mo sì gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ wọn.”
Esek 39:1-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ sí Gogu, kí ó sì wí pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè wí: Èmi lòdì sí ọ, Ìwọ Gogu, olórí ọmọ-aládé ti Meṣeki àti Tubali. Èmi yóò dá ọ padà, èmi yóò sì darí rẹ. Èmi yóò mú ọ wá láti jìnnàjìnnà ìhà àríwá, Èmi yóò rán ọ lòdì sí orí àwọn òkè gíga Israẹli. Nígbà náà èmi yóò lu ọrùn awọ rẹ ní ọwọ́ òsì rẹ, èmi yóò sì mú kí àwọn ọfà rẹ jábọ́ ni ọwọ́ ọ̀tún rẹ. Ìwọ yóò sì ṣubú ní orí àwọn òkè Israẹli, ìwọ àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ àti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn onírúurú ẹyẹ àti fún àwọn ẹranko igbó. Ìwọ yóò ṣubú ní gbangba pápá, nítorí tì mo ti sọ̀rọ̀, ni OLúWA Olódùmarè wí. Èmi yóò fi iná sí Magogu àti sí àwọn tí ń gbé ní agbègbè ilẹ̀ ibẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni OLúWA. “ ‘Èmi yóò sọ orúkọ mímọ́ mí di mí mọ̀ láàrín àwọn ènìyàn mì Israẹli. Èmi ki yóò jẹ́ kí orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yóò mọ̀ pé èmi OLúWA, èmi ni ẹni mímọ́ ní Israẹli. Ó ń bọ̀! Ó dájú pé yóò ṣẹlẹ̀, ni OLúWA Olódùmarè. Èyí yìí ni ọjọ́ tí mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. “ ‘Nígbà náà, àwọn ti ó ń gbé nì àárín àwọn ìlú tí ó wà ni Israẹli yóò jáde, wọn yóò sì lo àwọn ohun ìjà bi epo ìdáná yóò sì jó wọ́n kanlẹ̀—àpáta kéékèèkéé àti àpáta ńlá, àwọn ọfà, àwọn kùmọ̀ ogun àti ọ̀kọ̀ fún ọdún méje wọn yóò lò wọ́n bi epo ìdáná. Wọn kò ní nílò láti kó igi jọ láti inú pápá, tàbí gé e láti inú igbó, nítorí pé wọ́n yóò lo òhun ìjà ogun bi epo ìdáná. Wọn yóò sì kógun àwọn tí ó ṣe ìgárá sí wọn, wọn yóò sì bo ilé àwọn tí ó bo ilé wọn, ni OLúWA Olódùmarè. “ ‘Ní ọjọ́ náà èmi yóò sì fi ibi ìsìnkú fún Gogu ní Israẹli, ni àfonífojì àwọn ti ó rìn ìrìnàjò lọ sí agbègbè ilà oòrùn Òkun. Yóò di ojú ọ̀nà àwọn arìnrìn-àjò, nítorí Gogu àti gbogbo ìjọ rẹ̀ ni àwa yóò sin síbẹ̀. Nítorí náà, a yóò pè é ní Àfonífojì tí Ammoni Gogu. “ ‘Fún oṣù méje ní ilé Israẹli yóò fi máa sìn wọ́n láti ṣe àfọ̀mọ́ ilẹ̀ náà. Gbogbo ènìyàn ilẹ̀ náà yóò sìn wọ́n, ọjọ́ tí a yìn mi lógo yóò jẹ́ ọjọ́ ìrántí, ní OLúWA Olódùmarè wí. “ ‘Wọn yóò gbà àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́ lóòrèkóòrè láti ṣe àfọ̀mọ́ náà. Ọ̀pọ̀ yóò lọ káàkiri ilẹ̀ náà, ní àfikún pẹ̀lú wọn, àwọn tókù yóò sìn àwọn tí ó kú lórí ilẹ̀: Ní ìparí oṣù keje wọn yóò bẹ̀rẹ̀ wíwá kiri wọn. Bí wọ́n n lọ káàkiri ilẹ̀ náà ọ̀kan nínú wọn rí egungun ènìyàn, òun yóò gbé ààmì ńlá kalẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ rẹ títí àwọn asìnkú yóò fi sìn ín ní Àfonífojì Hamoni Gogu. (Bákan náà ìlú kan tí a ń pè ni Hamona yóò wà níbẹ̀). Nítorí náà wọn yóò wẹ ilẹ̀ náà:’ “Ọmọ ènìyàn èyí yìí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè wí pé: Pe gbogbo oríṣìíríṣìí ẹyẹ àti gbogbo àwọn ẹranko igbó jáde: ‘Kí wọn péjọpọ̀ láti gbogbo agbègbè sí ìrúbọ tí mó ń múra rẹ̀ fún ọ, ìrúbọ ńlá náà ní orí òkè gíga tí Israẹli. Níbẹ̀ ẹ̀yin yóò jẹ ẹran, ẹ̀yin yóò sì mú ẹ̀jẹ̀. Ẹ̀yin yóò jẹ ẹran-ara àwọn ènìyàn ńlá, ẹ o sì mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ-aládé ayé bí ẹni pé wọn jẹ́ àgbò àti ọ̀dọ́-àgùntàn, ewúrẹ́ àti akọ màlúù gbogbo wọn jẹ́ ẹran ọlọ́ràá láti Baṣani Níbi ìrúbọ tí mo ń múra kalẹ̀ fún yín, ẹ̀yin yóò jẹ ọ̀rá títí ẹ̀yin yóò fi jẹ àjẹkì, ẹ̀yin yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ títí ẹ̀yin yóò fi yó. Ní orí tábìlì mi ni àwa yóò ti fi ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin bọ yín yó, pẹ̀lú àwọn alágbára ńlá àti oríṣìíríṣìí jagunjagun,’ ni OLúWA Olódùmarè wí. “Èmi yóò ṣe àfihàn ògo mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì rí ìyà tí mo fi jẹ wọ́n. Láti ọjọ́ náà lọ, ilé Israẹli yóò mọ̀ pé èmi ni OLúWA Ọlọ́run wọn. Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì mọ̀ pé àwọn ènìyàn Israẹli lọ sí ìgbèkùn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi. Nítorí náà mo mú ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, mo sì fi wọn lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, gbogbo wọn sì ṣubú nípasẹ̀ idà. Mo ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí àìmọ́ àti àìṣedéédéé wọn, mo sì mú ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn.