Esek 37:2-5
Esek 37:2-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si mu mi rìn yi wọn ka: si wò o, ọ̀pọlọpọ ni mbẹ ni gbangba afonifojì; si kiyesi i, nwọn gbẹ pupọpupọ. O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, egungun wọnyi le yè? Emi si wipe, Oluwa Ọlọrun, iwọ li o le mọ̀. O tun wi fun mi pe, Sọtẹlẹ sori egungun wọnyi, si wi fun wọn pe, Ẹnyin egungun gbigbẹ, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun egungun wọnyi; Kiyesi i, emi o mu ki ẽmi wọ̀ inu nyin, ẹnyin o si yè
Esek 37:2-5 Yoruba Bible (YCE)
Ó mú mi la ààrin wọn kọjá; àwọn egungun náà pọ̀ gan-an ninu àfonífojì náà; wọ́n sì ti gbẹ. OLUWA bá bi mí léèrè, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, ǹjẹ́ àwọn egungun wọnyi lè tún jí?” Mo bá dáhùn, mo ní, “OLUWA, ìwọ nìkan ni o mọ̀.” Ó bá sọ fún mi pé, “Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn egungun wọnyi, kí o wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin egungun gbígbẹ wọnyi, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí’. Ó ní: ‘N óo mú kí èémí wọ inú yín, ẹ óo sì di alààyè.
Esek 37:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó mú mi lọ síwájú àti sẹ́yìn láàrín wọn, èmi sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn egungun ní orí ilẹ̀ àfonífojì, àwọn egungun tí ó gbẹ gan. OLúWA sì bi mí léèrè, “Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ àwọn egungun wọ̀nyí lè yípadà di àwọn ènìyàn bí?” Èmi sì wí pé, “Ìwọ OLúWA Olódùmarè, ìwọ nìkan ni o lè dáhùn sí ìbéèrè yìí.” Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn egungun kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin egungun gbígbẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA! Èyí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè wí fún àwọn egungun wọ̀nyí: Èmi yóò mú kí èémí wọ inú yín ẹ̀yin yóò sì wá di ààyè.