Esek 36:16-18
Esek 36:16-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, Ọmọ enia, nigbati ile Israeli ngbe ilẹ ti wọn; nwọn bà a jẹ nipa ọ̀na wọn, ati nipa iṣe wọn: ọ̀na wọn loju mi dabi aimọ́ obinrin ti a mu kuro. Nitorina emi fi irúnu mi si ori wọn, nitori ẹ̀jẹ ti wọn ti ta sori ilẹ na, ati nitori ere wọn ti wọn ti fi bà a jẹ.
Esek 36:16-18 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ń gbé ilẹ̀ wọn, wọ́n fi ìwà burúkú ba ilẹ̀ náà jẹ́. Lójú mi, ìwà wọn dàbí ìríra obinrin tí ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́. Mo bá bínú sí wọn gan-an nítorí ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ta sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà ati oriṣa tí wọ́n fi bà á jẹ́.
Esek 36:16-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Síwájú sí i ọ̀rọ̀ OLúWA tọ̀ mí wá: “Ọmọ ènìyàn, nígbà tí àwọn ènìyàn Israẹli: ń gbé ní ilẹ̀ wọn, wọ́n bà á jẹ́ nípa ìwà àti ìṣe wọn. Ìwà wọn dàbí nǹkan àkókò àwọn obìnrin ni ojú mi. Nítorí náà mo tú ìbínú mi jáde sórí wọn nítorí wọn ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ti fi ère wọn ba a jẹ́.