Esek 31:4-9
Esek 31:4-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Omi sọ ọ di nla, ibú gbé e ga soke, o fi awọn odò nla rẹ̀ yi oko rẹ̀ ka, o si rán awọn odo kékèké rẹ̀ si gbogbo igbẹ́. Nitorina a gbe giga rẹ̀ soke jù gbogbo igi igbẹ́ lọ, ẹ̀ka rẹ̀ si di pupọ̀, awọn ẹ̀ka rẹ̀ si di gigùn nitori ọ̀pọlọpọ omi, nigbati o yọ wọn jade. Gbogbo ẹiyẹ oju ọrun kọ́ itẹ́ wọn ninu ẹ̀ka rẹ̀, ati labẹ ẹ̀ka rẹ̀ ni gbogbo ẹranko igbẹ́ bi ọmọ wọn si, ati labẹ ojiji rẹ̀ ni gbogbo awọn orilẹ-ède nla ngbe. Bayi li o ni ẹwà ninu titobi rẹ̀, ninu gigùn ẹ̀ka rẹ̀: nitori ti egbò rẹ̀ wà li ẹbá omi nla. Awọn igi kedari inu ọgbà Ọlọrun kò le bò o mọlẹ: awọn igi firi kò dabi ẹ̀ka rẹ̀, awọn igi kẹsnuti kò si dabi ẹ̀ka rẹ̀; bẹ̃ni kò si igikigi ninu ọgbà Ọlọrun ti o dabi rẹ̀ li ẹwà rẹ̀. Emi ti ṣe e ni ẹwà nipa ọ̀pọlọpọ ẹ̀ka rẹ̀: tobẹ̃ ti gbogbo igi Edeni, ti o wà ninu ọgbà Ọlọrun, ṣe ilara rẹ̀.
Esek 31:4-9 Yoruba Bible (YCE)
Omi mú kí ó dàgbà, ibú omi sì mú kí ó ga. Ó ń mú kí àwọn odò rẹ̀ ṣàn yí ibi tí a gbìn ín sí ká. Ó ń mú kí odò rẹ̀ ṣàn lọ síbi gbogbo igi igbó. Nítorí náà, ó ga sókè fíofío, ju gbogbo igi inú igbó lọ. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tóbi, wọ́n sì gùn, nítorí ọpọlọpọ omi tí ó ń rí. Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, pa ìtẹ́ sára àwọn ẹ̀ka rẹ̀. Lábẹ́ rẹ̀ ni gbogbo ẹranko inú igbó ń bímọ sí. Gbogbo orílẹ̀-èdè ńláńlá sì fi ìbòòji abẹ́ rẹ̀ ṣe ibùgbé. Ó tóbi, ó lọ́lá ẹ̀ka rẹ̀ sì lẹ́wà nítorí pé gbòǹgbò rẹ̀ wọ ilẹ̀ lọ, ó sì kan ọpọlọpọ omi nísàlẹ̀ ilẹ̀. Igi kedari tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun kò lè farawé e. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ka igi firi kò sì tó ẹ̀ka rẹ̀. Ẹ̀ka igi kankan kò dàbí ẹ̀ka rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí igikígi ninu ọgbà Ọlọrun tí ó lẹ́wà bíi rẹ̀. Mo dá a ní arẹwà, pẹlu ẹ̀ka tí ó pọ̀. Gbogbo igi ọgbà Edẹni, tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun sì ń jowú rẹ̀.
Esek 31:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Omi mú un dàgbàsókè: orísun omi tí ó jinlẹ̀ mú kí o dàgbàsókè; àwọn odo rẹ̀ ń sàn yí ìdí rẹ̀ ká, ó sì rán ìṣàn omi rẹ̀ sí gbogbo igi orí pápá. Nítorí náà ó ga sí òkè fíofío ju gbogbo igi orí pápá lọ; ẹ̀ka rẹ̀ pọ̀ sí i: àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gùn, wọn tẹ́ rẹrẹ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi. Ẹyẹ ojú ọ̀run kọ ilé sí ẹ̀ka rẹ̀ gbogbo ẹranko igbó ń bímọ ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀; gbogbo orílẹ̀-èdè ńlá ń gbé abẹ́ ìji rẹ̀. Ọláńlá ní ẹwà rẹ̀ jẹ́, pẹ̀lú títẹ́ rẹrẹ ẹ̀ka rẹ̀, nítorí gbòǹgbò rẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ sí ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi wà. Àwọn igi kedari nínú ọgbà Ọlọ́run kò lè è bò ó mọ́lẹ̀; tàbí kí àwọn igi junifa ṣe déédé pẹ̀lú ẹ̀ka rẹ̀, tàbí kí a fi igi títẹ́ rẹrẹ wé ẹ̀ka rẹ̀, kò sí igi nínú ọgbà Ọlọ́run tí ó dà bí rẹ̀ ní ẹwà rẹ̀. Mo mú kí ó ní ẹwà pẹ̀lú ẹ̀ka lọ́pọ̀lọpọ̀ tó fi jẹ́ ìlara àwọn igi gbogbo ní Edeni tí í ṣe ọgbà Ọlọ́run.